Agbarijọpọ awọn musulumi nipinlẹ Ọyọ ti bu ẹnu atẹ lu ofin to niṣe pẹlu Sharia eyi ti wọn ni awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi tiwọn ṣọṣẹ nijọba ibilẹ Oriire n beere fun ti wọn si n sọ pe awọn ọdaran naa o kii ṣe musulumi bẹẹ ni wọn o huwa ẹkọ Islam.
Awọn ajinigbe naa ti wọn ṣe ikọlu si awọn ile-iwe mẹta ni awọn agbegbe Esinele, Yawota ati Alawusa l’ọjọ kẹẹdogun oṣu karun ọdun yii ni awọn abala kọọkan ninu awujọ pe wọn n beere fun iyọnda awọn ọgagun agbesunmọmi, sisan owo idasilẹ, ọkọ Hilux meji ati ṣiṣe ofin Sharia ki wọn to da awọn ti wọn jigbe silẹ.
Ninu atẹjade kan ti alaga ati akọwe agbarijọpọ awọn musulumi nipinlẹ Ọyọ buwọlu ni wọn ti ṣapejuwe iwa awọn agbesunmọmi naa gẹgẹ bii iwa ọdaran to lodi patapata si ẹkọ Islam.
Awọn agbarijọpọ naa ni igbiyanju awọn ajinigbe naa lati fi ẹsin ti iwa laabi wọn lẹyin yatọ gedengbe si Islam. Wọn ni Islam kọ ijinigbe, igbesunmọmi ati fifi ipa gba owo lọwọ awọn araalu.
Atẹjade naa tẹsiwaju pe ofin Sharia gidi maa n ṣe igbelaruge fun idajọ ododo, alaafia ati pataki ẹmi ọmọ eeyan leyi to jina si igbagbọ awọn ọdaran naa.
Wọn fikun pe awọn agbesunmọmi naa o le sọrọ l’orukọ gbogbo awọn musulumi bẹẹ ni wọn n rọ awọn ẹṣọ alaabo lati tubọ gbiyanju ki wọn le doola awọn ti wọn wa ni gbekun awọn ajinigbe.
Ọrọ yii jẹyọ bi ọpọ awọn eeyan ṣe n bẹru lori eto aabo l’orilẹede Naijiria paapaa julọ alaafia awọn ọmọ ati olukọ ti wọn wa lakata awọn ajinigbe.