Alabojuto Agba ati Oludasilẹ ijọ Deeper Christian Life Ministry ti ọpọ mọ si ijọ Deeper Life – Oluṣọ Aguntan (Pasitọ) William Folorunsho Kumuyi ti ṣalaye pe oun ko ni l’ọkan lati gbe akoso ijọ naa le eyikeyi ninu awọn ọmọ rẹ l’ọwọ l’ẹyin ti oun ba kuro.
“Ọpọ eniyan lo n m’efo pe, ṣe ọmọ rẹ ni yoo fa akoso ijọ le l’ọwọ? Ṣe ko ni wa akọbi rẹ ọkunrin rẹ ri, abi ọmọkunrin rẹ keji, ni’bo ni wọn wa? Nibo ni wọn gbe? Ṣe ko ni fa akoso ijọ si’lẹ?” Kumuyi wi.
Baba Kumuyi lo sọ eyi lasiko ijọsin laipẹ yii, gẹgẹ bii esi ọrọ si ahesọ kan to n lọ kiri pe ọkan ninu awọn ọmọ rẹ lo n gbero ati gbe akoso ijọ Deeper Life fun.
Gbajugbaja oluṣọ aguntan naa jẹ ko di mimọ pe ijọ Ọlọrun kii ṣe dukia abi ile-iṣẹ ẹni kọọkan ti eniyan le fa kalẹ fun ọmọ rẹ abi ẹni to ba fẹ lati j’ogun, nitori Jesu kristi lo ni ijọ rẹ, ẹmi mimọ si ni yoo dari ibi ti akoso ijọ yoo bọ si l’ẹyin to ba ṣetan.
Siwaju si, Kumuyi ṣ’apẹrẹ pẹlu Peteru, Pọọlu ati Johanu ninu Bibeli gẹgẹ bii aṣaaju ijọ ṣugbọn ti wọn ko j’ogun ijọ fun awọn ọmọ wọn.