Gbajugbaja onkọrin takasufe, David Adeleke ti gbogbo eeyan mọ si Davido ṣe ayipada ere rẹ nibi ayẹyẹ imura 2026 FIFA World Cup si ẹbẹ fun idajọ ododo.
Nigba to bọ si ori itage nilu Amẹrika nibi ti ayẹyẹ naa ti waye onkọrin naa wọ aṣọ aranbara to fi buyi fun awọn ọmọ ati olukọ ti wọn jigbe nijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ.
Ninu fọnran kan ti wọn ṣe lẹyin itage leyi to ti n tanka bayi lo ti wọ aṣọ alawọ funfun leyi ti wọn kọ Naijiria sii. Lori aṣọ iyẹn lo wọ imii ti wọn fi bọtini kọ orukọ awọn eeyan kọọkan ti wọn jigbe ati awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ikọlu naa pẹlu ọrọ ti wọn fi le pe ki wọn da awọn ọmọ naa pada.
Davido lo fi iyẹn ke pe awọn ara oke okun si eto aabo to mẹhe lorilẹde Naijiria.
Ko to bọ sori itage ni onkọrin naa fi aidunnu rẹ han lori iṣẹlẹ naa to si n rawọ ẹbẹ si ijọba lati tẹpa mọ igbiyanju ati doola awọn ọmọ naa.
O wa gba l’adura pe ki Ọlọrun duro ti awọn mọlẹbi awọn ti wọn wa ni igbekun awọn ajinigbe.