Ọfọ Ṣẹ L’agbo’le Tiata, Agba-Ọjẹ Oṣere – Kola Oyewọ Ja’de L’aye

Gbajugbaja agbaojẹ oṣerekunrin elere ori itage ati ti sinima agbelewo, dokita Kọla Oyewọ to kopa ninu sinima Ṣaworoide lo ti dagbere f’aye lẹni ọgọrin ọdun.

Iku agbaojẹ oṣerekunrin naa ni wọn kede l’ọjọ Jimoh. Ninu ọrọ kan ti ọmọ rẹ, Adetoyese Oyewo fi lede lori itakun ibanidọrẹ Facebook rẹ lo ti ṣapejuwe baba rẹ gẹgẹ bii ẹni to gbe igbe-aye ifẹ, ọgbọn, okun ati aanu to si n fi ibanujẹ rẹ han lori iku baba naa.

Oṣerekunrin Kunle Afod lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ to ti kede iku Oyewọ lo ti gboriyin fun f’awọn iṣẹ to gbe ṣe lagodo tiata l’orilẹede Naijiria.

Oyewọ lo ti n ba ipa fa lati bii ọdun diẹ sẹyin leyi to sọ pe o ṣokunfa k’oun ma le ṣe ere sinima mọ bii ti tẹlẹ latari ailera naa.

A bi Kọla Oyewọ ni ọjọ kẹtadinlọgbọn ọdun 1946 silu Oba-Ile. O bẹrẹ iṣẹ tiata pẹlu ikọ ere ori itage Oyin Adejobi ni ọdun 1964 to si gbera lati bẹ ṣe gudugudu meje yaya mẹfa nidi iṣẹ tiata fun ọgọfa ọdun le diẹ.

Yatọ si idi iṣẹ tiata, Oyewọ ṣe iṣẹ takuntakun nidi ẹkọ pẹlu bo ṣe kawe gboye dokita ninu ere ori itage to si n kọ awọn ọmọ l’ẹkọ ni awọn ile-ẹkọ giga loriṣiriṣi.

Awọn ẹbi rẹ ti wa beere fun adura ati atilẹyin l’asiko ti wọn n kẹdun baba wọn to lọ.

Ọpọ awọn ololufẹ ati awọn oṣere ni wọn ti kẹdun iku agbaojẹ naa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search