Ọrọ Owo Ma Ti Dija Silẹ Laarin Shallipopi Ati Ọga Rẹ Tẹlẹ Kẹ, Bayi Lo Ṣe Ṣẹlẹ

Gbajugbaja onkọrin Crown Uzama ti gbogbo eeyan mọ si Shallipopi ti f’ẹsun ṣiṣe ayederun ati tita awọn awo orin rẹ lọna aitọ si ile-iṣẹ kan l’oke okun kan ọga ile-iṣẹ orin to wa tẹlẹ Damilola Akinwunmi ti gbogbo eeyan mọ si Dapper.

Lori ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ X rẹ lo ti ni o di owo to ri nibi awọn orin mẹrindinlaadọta t’oun kọ mu bẹẹ lo ta awọn akojọpọ orin oun.

Shallipopi ni adehun ọdun kan l’oun buwọlu pẹlu ile-iṣẹ naa ṣugbọn Dapper ji ibuwọlu oun lati fi ṣe adehun ọlọdun mẹwa.

O tẹsiwaju pe ayederu ibuwọlu yii na lo fi ta awọn akojọpọ orin oun fun ile-iṣẹ kan nilu oyinbo to si ko owo rẹ s’apo.

Onkọrin naa f’ẹsun kan ọga rẹ tẹlẹ pe gbogbo owo to ri n’idi orin oun lo gbẹsẹ le, to si ni k’oun ṣiṣẹ takuntakun fun ọjọ-ọla to da.

O ni lootọ oun le jẹ ọmọ at’apata-dide ṣugbọn oun o gọ. Shallipopi ni oun ti ṣetan lati fi ọrọ naa to awọn ajọ to n risi iṣowo ilu kumọkumọ (EFCC) l’eti.

Shallipopi ni oun fẹ ki ajọ EFCC, ijọba, awọn oniroyin ati gbogbo awọn ara adulawọ pata mu ọrọ naa l’ọkunkundun.

Shallipopi lo ja gbangba nidi orin ni ọdun 2023, to si n gbe orin jade labẹ ile-iṣẹ orin Dapper Music.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search