Ile-ẹjọ giga apapọ ti ilu Abuja ti paṣẹ ki wọn fi kele ofin gbe ajafẹtọ ati adije-du’po aarẹ l’abẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC), Omoyele Sowore latari pe ko yọju sibi ipẹjọ rẹ.
Ṣoworẹ, ẹni to yẹ ko bẹrẹ ijẹjọ rẹ lori ẹsun meji ọtọọtọ to da le idunkokomọni lori ẹrọ ayelujara latari ọrọ kan to fi le’de l’ori itakun ibanidọrẹ rẹ to ti pe Aarẹ Bọla Tinubu ni ọdaran.
Olujẹjọ naa lo ni oun maa ṣ’oju ara oun ni’le-ẹjọ l’ẹyin ti ikọ awọn agbẹjọro rẹ yọwọ ninu ẹjọ naa ṣugbọn nigba ti ijẹjọ naa tẹsiwaju l’oni, Ṣoworẹ o yọju si’le-ẹjọ bi o ti lẹ jẹ pe o fi lẹta ranṣẹ pe oun rin irin-ajo lọ si Eko l’ati wa awọn agbẹjọro ti yoo ṣ’oju oun ninu ẹjọ naa.
Lẹyin ti awọn ọlọpa ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa (DSS) beere fun idapada beeli rẹ ti ile-ẹjọ gba tẹlẹ ati anfaani lati tun fi ṣikun ofin gbe, adajọ Mohammed Umar buwọlu ibeere naa.
Ni ibẹrẹ ẹjọ naa ni Sowore ti kọkọ beere pe ki adajọ to wa nidi ẹjọ naa fi silẹ ki adajọ agba le gbe ẹjọ naa fun ẹlomiiran gẹgẹ bi o ṣe tọ labẹ ofin, to si n fi iṣẹlẹ bi adajọ naa ti ni ki agbẹjọro oun kunlẹ niwaju ile-ẹjọ ṣe itọkasi.
O tẹsiwaju pe nitori igbẹjọ ojoojumọ ati iwa adajọ naa ni awọn agbẹjọro oun ṣe sa fun ẹjọ naa.
Ti ẹ o ba gbagbe, ni ọjọ keji oṣu kejila ọdun to kọja ni Ṣoworẹ bẹbẹ ni’le-ẹjọ pe oun ko jẹbi lẹyin ti ajọ DSS wọ dewaju ile-ẹjọ fun ẹsun l’at’ari esi to fi l’ori ẹrọ ayelujara ni’pa ọrọ ti Aarẹ Tinubu sọ pe iṣejọba oun ti f’opin si iwa jẹgudujẹra l’orilẹ-ede Naijira.