Mo N Duro De Aṣẹ Lat’ọwọ Ijọba Apapọ Lati Kogun Ja Awọn Agbesunmọmi Lẹkun Guusu Iwọ Oorun – Sunday Igboho

Gbajumọ ajijangbara nilẹ Yooba, Sunday Adeyemo ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho lo ti sọ pe oun n duro de aṣẹ lat’ọdọ ijọba apapọ fun ẹṣọ alaabo tiẹ iyẹn Iru Ekun Security Network lati gbina ya ki wọn le koju awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi tọ n ṣọṣẹ ni ẹkun Iwọ-oorun guusu orilẹede yii.

Bakan naa lo fi kun pe oun ṣetan lati tẹle ofin ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fi lede lati bẹ iṣẹ awọn ẹṣọ alaabo aladani wo.

Igboho sọ eyi ninu ọrọ kan to fi lede nilu Ibadan pẹlu afikun pe gbogbo iwe to ṣe koko lati bẹrẹ ikọ ẹṣọ alaabo naa lo ti pe perepere to si ti de iwaju ijọba apapọ bayi.

O tẹsiwaju pe awọn ti ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo gbogbo lorilẹede Naijira lati ri pe awọn ajinigbe ati ẹlẹkẹru agbesunmọmi yoo jẹ ohun igbagbe paapaa julọ ni awọn igberiko wa.

O wa gbe oṣuba kaare fun Aarẹ Bola Tinubu fun iṣẹ takuntakun lati mu atunṣe ba awọn ẹṣọ alaabo paapaa julọ ni ẹkun guusu iwọ oorun.

Igboho wa fi kun pe lai si aabo ati alaafia to peye ko le si idagbasoke paapaa julọ awọn igberiko to jẹ pe iṣẹ agbẹ ni wọn yan laayo ati pe o le ṣokun fa ki ounjẹ ma to nilu.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search