O Gbẹnu Tan! Denrele Onitiata Gbe Ara Rẹ Ni’yawo

O Gbẹnu Tan! Denrele Onitiata Gbe Ara Rẹ Ni'yawo

Gbajumọ sọrọsọrọ ati oṣerekunrin, Adenrele Oluwafemi Edun ti ọpọ eeyan mọ si Denrele lo ti ṣalaye idi to ṣe pinu lati gbe ara rẹ niyawo gẹgẹ bii isami ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marundinlaadọta (45).

Denrele lo ti fa awuyewuye lori ẹrọ ayelujara lẹyin to fi fọnran kan lede leyi to fi kede igbeyawo to ṣe pẹlu ara rẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni igbesẹ naa n sami ayẹyẹ ifẹ fun ara ẹni, suuru ati ọpọlọpọ awọn nkan ti oun ti la kọja laye lati gbogbo ọdun yii sẹyin.

Nigba to n boju wo irin-ajo rẹ lati ẹyin wa lori bo ṣe di ilumọọka ati oun ti oju rẹ ri ko to la, o ni oun buyi fun ẹni to duro ti oun ninu gbogbo ilakaka naa.

O ni oun fẹ ẹnikan ṣoṣo to duro ti oun nigba gbogbo iyẹn oun gan-an gan-an nitori naa oun ni ọkọ ati iyawo.

Ikede yii lo ti fa awuyewuye lori ẹrọ ayelujara nigba ti awọn ololufẹ rẹ n ki pe o ni ifẹ ara rẹ bo ṣe yẹ ti wọn si n ki ku oriire ọjọ ibi naa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search