Igbakeji Aarẹ tẹlẹ ri, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lo ti ṣalaye idi to fi pa oti mimu ti, lẹyin aimọye ọdun to ti di atunbi. O sọrọ yii nibi ipade apero kan to waye ni Maryland ni orilẹ-ede Amẹrika, to da le kiko ara ẹni nijanu gẹgẹ bii adari.
Ninu alaye Ọṣinbajo, oun ko fi igba kankan ri ọti mimu gẹgẹ bi ẹsẹ abi oun ti ko tọ, paapaajulọ pẹlu pe Jesu Kristi sọ omi di ọti waini, ti oun a si mọ mu ọti waini abi bia lẹkọọkan.
Amọ ṣa, Ọṣinbajo ṣalaye pe iriri kan ti oun ni nilu Mogadishu ni orilẹ-ede Somalia lo sọ oun di ẹni to kọ ọti silẹ. O ni oun lọ ṣe awọn eto kan to fi mọ ijihinrere ni orilẹ-ede naa ni iriri naa waye.
“Mo fẹ lọ ra ọti ni ile faaji kan nitosi agbegbe nilu Mogadishu, ṣugbọn lọgan ti mo wolẹ sibẹ lawọn to n mu ọti bẹrẹ si ni gbe ọti pamọ nitori ti wọn rii mi gẹgẹ alufa ati olugbala wọn.” Ọṣinbajo jẹ ko di mimọ pe iṣẹlẹ yii gan-an ni pato lo yi oun lọkan pada kuro ninu mimu ọtí rara.