Ẹ Ma Fi Orukọ Mr. Ibu Lọ Awọn Eeyan Lọwọ Gba – Tenkobo

Ẹ Ma Fi Orukọ Mr. Ibu Lọ Awọn Eeyan Lọwọ Gba - Tenkobo

Oṣerekunrin apanilẹrin, Fred Ebere ti gbogbo eeyan mọ si Tenkobo lo ti sọrọ tako arabinrin Stella Maris Okafor, iyawo gbajugbaja oṣere to di oloogbe, Mr. Ibu fun pe o jade wa beere iranlọwọ lori ayelujara.

O fi ẹsun kan Stella pe o fẹ fi orukọ ọkọ re lọ owo gba lọwọ awọn araalu bẹẹ lo ni ki oun ati awọn mọlẹbi to ku pese owo ti wọn ri nibi tita awọn ile ati ilẹ ti oloogbe naa fi silẹ lọ.

Tenkobo ni, nitori o jẹ iyawo gbajugbaja oṣere ko ni ko ma n’iṣẹ lọwọ.

 

Nigba to n sọrọ ninu fọnran kan to ti gbe ọrọ rẹ pẹlu awọn mọlẹbi Ibu s’ori ayelujara, o ni bi oun ṣe ri fọnran naa, inu bi oun gidi nitori naa l’oun ṣe pe akọbi Ibu l’ọkunrin to ku diẹ ko pe ọmọ ogoji ọdun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọmọ naa ba ara jẹ nigba to pe l’ori fọnran naa. O ni oun sunmọ oloogbe pẹkipẹki nitori naa, oun mọọ t’inu t’ode.

O ni kii ṣe igba akọkọ ti Stella maa ṣe iru nkan bayi re, ko da, o ṣe nigba ti Ibu wa laye t’oun si yanju rẹ.

Tenkobo tẹsiwaju lati sọ pe ọmọ obinrin inu fọnran naa kọ ni obinrin kan ṣoṣo ti Ibu bi nitori o ni ọmọ to pọ, ko da, akọbi rẹ l’obinrin ti n sunmọ ọgbọn ọdun.

O ni oun o binu si pe o jade wa tọrọ iranlọwọ ṣugbọn ko ma jẹ ko da bii pe Ibu o ṣiṣẹ silẹ. O ni o ṣeto fun ọjọ-ọla pẹlu owo to ri n’idi iṣẹ tiata ṣugbọn iṣoro to ni naa l’awọn ẹbi rẹ.

O tẹsiwaju lati beere pe ta lo ta awọn ohun ini ti Ibu fi silẹ ati pe kini wọn fi owo naa ṣe.

Tenkobo ni ki ẹnikẹni to ba fẹ ran-an lọwọ ni lọkan pe Ibu ṣe nkan to yẹ ko to ku.

Ti ẹ o ba gbagbe, awọn mọlẹbi Ibu ni wọn jade lori ayelujara lati sọrọ nipa bi nkan ti ṣe le fun wọn lẹyin iku rẹ, de’bi pe wọn o ri owo ile ati owo ile-iwe san.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search