Ẹgbẹ Oṣelu NDC Wọgi Le Ibura Fun Obi Ati Kwankwanso

Ẹgbẹ Oṣelu NDC Wọgi Le Ibura Fun Obi Ati Kwankwanso

Ẹgbẹ oṣelu NDC ti ya adije dupo aarẹ ẹgbẹ naa, Peter Obi ati igbakeji rẹ, Rabiu Kwankwanso s’ọtọ ninu ibura lati ma kuro ninu ẹgbẹ naa eyi ti wọn fẹẹ fi dena ki awọn tiwọn wọle idibo labẹ asia ẹgbẹ naa ṣi lọ sinu ẹgbẹ mii lẹyin ti wọn ba wọle tan.

Ẹni to jẹ akọwe apapọ fun ẹgbẹ naa, Ikenna Enekweizu lo sọ eyi di mimọ lori ẹrọ amohunmaworan nigba to n fesi si ọrọ t’awọn kan sọ pe ibura naa tako ofin ilẹ wa.

Ẹni to jẹ akọwe apapọ fun ẹgbẹ naa, Ikenna Enekweizu lo sọ eyi di mimọ lori ẹrọ amohunmaworan nigba to n fesi si ọrọ t’awọn kan sọ pe ibura naa tako ofin ilẹ wa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ifọwọsiwe ibura iṣootọ yii wa ninu ofin ẹgbẹ naa ti o si wa lati daabobo ẹgbẹ nibi ṣiṣi lọ to ti da ọpọlọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu ru latẹyin wa.

Enekweizu ko awọn aba pe eto ọhun o ba ofin mu danu to si n jiyan pe o tọna labẹ ofin fun awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn ba finu fẹdọ darapọ mọ ẹgbẹ kan-kan lati tẹle ofin ẹgbẹ naa.

O tẹsiwaju pe lootọ ofin ẹgbẹ kan nipa fun gbogbo adije lati buwọlu iwe ibura naa ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu NDC ti pinnu lati ya Obi ati Kwankwanso s’ọtọ ninu ofin naa.

O ṣalaye pe awọn to kan ẹgbẹ naa gbọn-gbọn ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ ati ipinlẹ ti wọn maa n kuro ninu ẹgbẹ ti wọn ba wa lẹyin idibo to gbe wọn wọle.

Ẹgbẹ oṣelu NDC ni wọn ṣẹṣẹ ṣaṣọloju igbesẹ lati dena ṣiṣi lọ ninu ẹgbẹ, ti wọn si n ṣalaye pe igbesẹ naa waye lati daabobo ẹgbẹ naa.

Awọn agbaagba ẹgbẹ naa fi idi rẹ mulẹ pe kikuro ninu ẹgbẹ to yan awọn adije sipo lẹyin ti wọn ba wọle tan lo ṣokunfa eto naa.

Enekweizu ni ẹgbẹ naa ṣetan lati fi ẹsẹ mulẹ daadaa ti wọn o si ni gba ki oloṣelu kan-kan fi ẹgbẹ naa ṣe irinsẹ lọ si ẹgbẹ mii.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search