Agbaojẹ oṣerekunrin, adari sinima to tun jẹ agbe sinima jade, Sunny Alli ti ni oun o nigbagbọ ninu ogun owo.
O ṣapejuwe ọpọ awọn sinima agbelewo ilẹ wa ti wọn fi n ṣafihan awọn ajẹ gẹgẹ bii eyi ti ko le ṣẹlẹ l’oju aye ti ko si ṣe gbagbọ.
Nigba to n sọrọ lori kikọ sinima, igbagbọ awọn eeyan lori nkan ti kii ṣe ootọ ati igbagbọ tirẹ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan, Sunny ni awọn ẹka kan wa t’oun maa n mọọmọ ma kọ itan lori wọn nitori kii ṣe nkan ti awọn eeyan le foju ri lati mọ pe ootọ ni.
O ni fun apẹrẹ, ko si ẹnikẹni to mọ bi awọn ajẹ ṣe ri bẹẹ ni ko si ẹri pe ibi kan ni ile ipade wọn tabi aṣọ bayi ni wọn n wọ nitori ko tii ṣ’oju ẹnikẹni. O fi kun pe, o ṣeeṣe f’oun lati kọ itan nipa ẹni to f’ọkọ gba eeyan to salọ nitori nkan to n ṣẹlẹ ni.
O tẹsiwaju lati sọrọ lori bi ọpọ nkan ti awọn eeyan n sọ nipa ogun owo o ṣe l’ẹsẹ nlẹ. O ni oun maa n bi awọn eeyan pe, nigba ti wọn ba sọ pe alujọnu lo gbe owo wa, ṣe wọn ni ẹrọ to n ṣe owo ni abi ile ifowopamọ ilẹ wa ni wọn ti lọ gbe wa, ṣugbọn wọn o kii ni idahun.
Sunny ni, oun n’ifẹ si awọn ere sinima to ba le ṣẹlẹ ju eyi ti ko si ẹri lati f’idi rẹ mulẹ lo.
Sunny Alli lo jẹ okan lara awọn ti wọn jọ bẹrẹ ikọ awọn elere Odunfa to si jẹ ọkan gboogi lara awọn oṣere ti wọn dantọ ninu sinima agbelewo ilẹ wa.
O bẹrẹ irin-ajo rẹ n’idi iṣẹ tiata ni ọdun 1992 ko to di pe o ja gbangba ni odun 2000.