Oṣerebinrin to tun gbajumọ lori ẹrọ ayelujara, Temi Otedola Ajibade lo ti fa ariwisi oriṣiriṣi lori ayelujara bayii lẹyin to gba pe lootọ, oun jẹ awọn anfaani pe wọn bi oun s’inu ọkan lara awọn idile to lọla julọ l’orile-ẹde yii.
Nigba to n sọrọ lori eto kan ti oun ati ọkọ rẹ, Mr. Eazi jọ n ṣe papọ, o sọrọ lori ọrọ ki wọn bi eeyan sinu idile ti orukọ ẹbi rẹ le ṣ’ilẹkun ati awọn anfaani to maa n wa pẹlu rẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o ni oun o f’igba kan-kan jiyan pe ọmọ inu ọrọ l’oun, to si ni o ma n ya oun lẹnu bi awọn eeyan o ba faramọ awọn daadaa ti wọn ba ri lat’ara orukọ mọlẹbi.
Temi ni, iyatọ wa ninu ki eeyan dagba pẹlu oore-ọfẹ ati ki eeyan dagba ninu anfaani ti orukọ ẹbi ṣi silẹ. O ni lootọ, oore-ọfẹ le fun eeyan ni awọn anfaani ati ohun ti eeyan nilo, ṣugbọn o yatọ si ẹni to ri anfaani latari awọn ilẹkun ti orukọ baba rẹ le ṣi lọ.
O ni o dara lati gba pe awọn anfaani naa wa ju ki eeyan maa parọ pe ko si lọ. O tẹsiwaju pe, ẹnikẹni o le ka oun nibi t’oun ti n sọ pe, oun o ri awọn anfaani kan-kan nitori orukọ oun.
Temi to jẹ ọmọ Ilumọọka oniṣowo, Femi Otedola, ni ọrọ rẹ ti wa fa ariwisi oriṣiriṣi lori ayelujara bayii. Bi awọn kan ṣe n gboriyin fun pe o sọ ootọ, ni awọn kan n sọrọ lori bi o ṣe ṣe pataki fun gbogbo eeyan lati ri anfaani kan naa lai fa’ri apa kan, da kan si.
Temi Otedola Ajibade lo wọ agbo tiata ni ọdun 2020. Ni ọdun to kọja lo fẹ gbajugbaja olorin takasufe, Mr. Eazi, ti wọn si n r’eti ọmọ bayii.