Mo Ti Ba Iyawo Ile Lasepọ Ri Daadaa – Brymo Jẹ’wọ

Mo Ti Ba Iyawo Ile Lasepọ Ri Daadaa - Brymo Jẹ'wọ

Irawọ olorin ọmọ ilẹ wa Olawale Ashimi ti ọpọ awọn eeyan mọ si Brymo lo ti tu aṣiri pe oun ti fẹ awọn iyawo ile ri daadaa, de’bi pe gbajugbaja ogbontarigi olorin miiran 2Face Idibia ti bi iyawo rẹ atijọ iyẹn Annie Macaulay leere l’oju oun boya Brymo ti ṣi l’aṣọ wo ri.

L’ori eto kan pẹlu ile-iṣẹ NotJustOkay to ja’de l’anaa ọjọ Isẹgun (Tuesday) ni Brymo ti mẹnuba eyi gẹgẹ bii ara awọn iriri igbesiaye rẹ l’atẹyin wa to gbe dẹbi to de l’onii.

 

Brymo ninu alaye rẹ ni l’asiko igba ti ogo oun kọkọ bu ja’de ti orin oun bẹrẹ si ni l’okiki, eyi fa ọpọlọpọ awọn obinrin to ju oun lọ rọ’gba yi oun ka, ti ọpọ a si parọ pe awọn ti pinya pẹlu ọkọ wọn botilẹjẹ pe wọn ṣi wa ni’le ọkọ.

Brymo ni ẹkọ nla ni iriri pada jẹ f’oun l’eyi to fa ọrọ amọran rẹ f’awọn ogo to n bọ l’ẹyin lati ṣọra ṣe pẹlu awọn iyawo ile nitori ewu nla to le ti idi rẹ yọ, ohun to si le mu ẹmi lọ ni.

O tun ṣ’apẹrẹ iyawo ile kan to ko oun sinu iyọnu tan diẹ lo ku, at’ojubọ aburu lo fẹ fa oun sinu rẹ.

Ohun awọn iriri naa lo buru debi pe 2face Idibia agba olorin miiran fi ni lati maa beere l’ọwọ aya rẹ tẹlẹ boya ohun ati Brymo ti ni nnkan pọ ri.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search