Ile-ẹjọ giga kan nilu Abuja fun aarẹ tẹlẹri lorilẹede yii, Goodluck Jonathan ni iyọnda lati dije dupo aarẹ l’ọdun 2027.
Ninu idajọ kan ri Adajọ, Peter Lifu gbe kalẹ lo ti wọn itanran ogun miliọnu fun agbẹjọro Johnmary Jideobi to gbe ẹjọ naa wa bẹẹ lo pa l’aṣẹ ko san fun Adajọ Agba ilẹ wa.
Adajọ Lifu ni agbẹjọro naa o ni agbara labẹ ofin lati mu ẹsun naa wa siwaju ile-ẹjọ nitori ọrọ naa o kan bẹẹ ni ko si nkan ti idije Jonathan ninu idibo ọdun 2027 fẹ ṣe fun.
O tẹsiwaju pe ile-ẹjọ giga nilu Yenagoa ati ile-ẹjọ kotẹmilọrun ti fidi rẹ mulẹ pe Jonathan ni anfaani lati dije.
O ṣapejuwe ẹjọ naa gẹgẹ bii aṣilo agbara ile-ẹjọ bẹẹ lo da ẹbẹ Jideobi lati ṣe ipaarọ adajọ.
Ẹwẹ, igun ẹgbẹ oṣelu PDP ti Kabiru Tanimu Turaki n lewaju fun ni wọn ti fun Jonathan ni iyọnda lati dije dupo gẹgẹ bii oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.