Agba oṣerekunrin, Jim Iyke lo ti ni awọn alujọnu ni wọn kun agbo amuludun ti wọn si n lo lati gba awọn ẹmi eṣu laye.
Nibi ifọrọwanilẹnuwo kan, Iyke ni ọpọ awọn ti wọn wa ni agbo amuludun l’oni ni wọn n sin ara wọn, ti wọn si n fi ara wọn pe Ọlọrun kekere to si jẹ iwa ẹmi eṣu.
Oṣerekunrin naa ni laye igba kan, oun maa n ro pe oun yatọ nitori awọn kan maa n daku ti wọn ba ri oun. O ni nigba t’oun mọ Ọlọrun tan l’oun mọ pe niṣe l’oun n sin ara oun dipo Ọlọrun.
O ṣalaye pe ọpọlọpọ akitiyan ati ifọkansi ni ẹnikẹni l’agbo amuludun fi le ni ajọṣepọ pẹlu Ọlọrun ti wọn o fi ni maa sin ara wọn tabi ṣe wu iwa ẹlẹmi eṣu.
O tẹsiwaju pe nitori ati ṣe igbelarugẹ iwa buburu awọn ẹlẹmi eṣu ni wọn ṣe da agbo amuludun silẹ. O ni ko si nkankan l’agbo amuludun to bu’yi kun Ọlọrun.
Jim Iyke ti orukọ rẹ gan gan jẹ James Ikechukwu Esomugha lo ja gbangba nidi iṣẹ tiata ni ọdun 1998, to si jẹ ọkan lara awọn to n lewaju ninu ere sinima agbelewo.