Ah! Oju Ri To, Ọjọ Mẹrin Ni Mo Lo L’atimọle Ọlọpa Lai Jẹ Lai Mu – Peller

Ah! Oju Ri To, Ọjọ Mẹrin Ni Mo Lo L'atimọle Ọlọpa Lai Jẹ Lai Mu - Peller

Agbefọnranjade l’ori ayelujara, Habeeb Hamzat ti gbogbo eeyan mọ si Peller lo ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri l’agọ ọlọpa, to si n ni oun o jẹ bẹẹ l’oun o wẹ fun ọjọ mẹrẹrin t’oun lo ni’bẹ.

Peller ni ọlọpa gbe ni ọjọ jimoh to kọja l’agbegbe Lekki n’ipinlẹ Eko lẹyin ariyanjiyan pẹlu awọn ọlọpa lori ọkọ ti o ni idanimọ ọkọ ati gilaasi ọkọ dudu.

Lẹyin ti wọn da silẹ ni Peller fi ọrọ lede lori itakun ibanidọrẹ Snapchat rẹ lati ṣalaye ohun oju rẹ ri.

 

O ni oun o le fi oju oun sita lọwọ yii nitori oju oun o ṣe ri bayi. O ṣalaye pe, o fẹ to ọjọ mẹrin t’oun fi sun ni sẹẹli, eyi ti ko ṣẹlẹ si oun ri.

Peller ni koda, awọn ti wọn jọ wa ni sẹẹli da oun mọ, ti wọn si fun oun ni inagijẹ 001. O fi kun pe fun odidi ọjọ mẹrin oun o jẹ, bẹẹ l’oun o mu.

O ni, iriri yii ti jẹ k’oun tubọ maa ṣọra nitori bayi, oun maa ri pe oun o ko si wahala kan-kan mọ nitori igbeyawo oun to n bọ lọna.

Ninu fọnran kan to jade lẹyin ti ọlọpa gbe ni Peller ti n ba awọn ọlọpa jiyan lori pe wọn ṣe oun bi ko ṣe yẹ ati pe wọn fa oun l’aṣọ ti wọn si gbe ibọn le oun lori ki wọn to fi ṣikun ofin gbe. O tẹnpẹlẹ mọ pe, oun ṣẹṣẹ ra ọkọ naa ni.

Peller lo f’oju ba ile-ẹjọ l’ọjọ iṣẹgun pẹlu Bello Oladipo ti wọn jọ fi ẹsun kan lori ẹsun mẹta ọtọọtọ to da le idinamọ awọn ọlọpa lati ṣiṣẹ wọn, iwa to le da omi alaafia ilu ru ati idipampa lati ṣẹ s’ofin.

Lẹyin eyi ni adajọ gba beeli rẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira, ki wọn to fi silẹ ko maa lọ.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search