Kọnbọki! Igbeyawo Akin Ọlaiya Keji Tuka Laipe Ọdun Kan
Gbajugbaja arẹwa oṣerekunrin, Akin Ọlaiya lo ti bọ si’ta wa sọ f’aye pe igbeyawo rẹ to ṣe pẹlu iyawo keji iyẹn Nafeesat Pheenah Hammed ni ilu Ibadan ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2025 to kọja lo ti tuka bayii.
Ninu lẹta kan ti oṣere naa fi si’ta l’ori ayelujara lo ṣalaye ni’pa ituka igbeyawo alariwo naa to wa’ye l’ọdun to lọ.
Ohun iyanu julọ ninu iṣẹlẹ yii ni bi igbeyawo to ṣẹṣẹ tuka yii ṣe da ọpọ họwu-họwu silẹ nipa ọrọ igbesiaye ati ile oṣere naa ti ọpọ ko si reti irufẹ iroyin bayii lati akata wọn.
Ninu alaye ti Ọlaiya ṣe ninu lẹta naa lo ti pe ṣebi ode kan ni ilu Eko lo yẹ ki ohun ati aya ti wọn ṣẹ tuka yii jọ lọ gẹgẹ bii l’ọkọo-l’aya ṣugbọn ti obinrin naa pe oun ko lọ mọ.
Si iyalẹnu Ọlaiya, ni’gba ti yoo fi de lati irin-ajo naa, aya rẹ ti pa’lẹ gbogbo ẹru rẹ mọ kuro ni’le, to si ti fi ile ọkọ rẹ si’lẹ. Ọlaiya ni oun gbiyanju gidi lati jẹ ki obinrin naa pada si’le oun ṣugbọn to yari Kan’lẹ pe oun ko fẹ igbeyawo naa mọ.
Ọlaiya tẹsiwaju pe, oun tun gbiyanju fi ọrọ lọ awọn mọlẹbi obinrin naa boya wọn le yanju ọrọ naa ṣugbọn ti gbogbo igbiyanju naa já si pabo.
Oṣere naa ninu lẹta to fi lede ṣalaye pe lẹyin ti ipa ti pin l’ori ati da igbeyawo naa pada ṣugbọn ti iyawo kọ jalẹ, ọkunrin naa pe oun lo anfaani lẹta naa lati kede fun gbogbo aye pe oun ati aya rẹ tẹlẹ Nafeesat Pheenah Hammed kii ṣe l’ọkọ-l’aya mọ.
Ni bayii ọgọrọ awọn eniyan l’ori ayelujara ati ni’gboro lo ti n jẹ ọrọ naa l’ẹnu bii guguru pẹlu oniruuru iwoye.