Ẹ Wa Gbọ Ohun To Ṣẹlẹ Laarin Baraka Ati Mosun Filani

Ẹ Wa Gbọ Ohun To Ṣẹlẹ Laarin Baraka Ati Mosun Filani

Oṣerekunrin Oluwole Cole, ti inagijẹ rẹ n jẹ Baraka ti ni oṣere ẹgbẹ rẹ, Mosun Filani jẹ ẹni to ni igberaga to dẹ bajẹ. O sọ eyi nibi ifọrọwanilẹnuwo kan ti wọn pe si.

Nigba to n sọ ohun to mọ nipa Mosun Filani, o ni Mosun jẹ ẹnikan to ni igberaga to dẹ bajẹ gidi gan ni.

O ṣalaye iriri rẹ pẹlu oṣere naa ni ibi ere kan to ni Mosun ti ṣ’iwa hu si awọn ọga rẹ, Kunle Afod ati oloogbe, Murphy Afọlabi.

Baraka ni, nigba naa, oṣere Fathia Balogun lo mu Mosun ni ọmọ afẹ rẹ. O fi kun pe, lẹyin to sọrọ si awọn agba oṣere naa, Mr. Latin ati awọn eeyan mii ti ọrọ naa ṣ’oju bẹ oun lati jẹ ki wọn ba wi nitori wọn mọ pe oun o ki n gba igbakugba.

Oṣere naa ni nigba ti asiko to lati ya iṣẹ, oun ni ko si aaye afi ti wọn ba le Mosun jade. O ṣalaye pe bi o ti lẹ jẹ pe, Fathia wa lori iduro, oun sọ fun Mosun pe, ko le maa wuwa ẹni ti wọn o tọ nitori o ni ẹni to n kin lẹyin, ati pe ọjọ ori gan ni oun n wo mọ Fathia lara.

O ni nigba ti oun sọ eyi ni oṣerekunrin Lala wa bẹrẹ sii bẹ oun lori ọrọ naa.

Mosun Filani lo ti wa f’esi bayi pẹlu fọnran kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ. Labẹ ariwisi fọnran yii lo ti kọ pe, onikaluku lo ni ero tiwọn, ṣugbọn aṣiṣe ti yoo ga ju ni ki ẹnikẹni jẹ ki ero ẹnikan jẹ gaba lori aye wọn.

Ọrọ yii lo ti mu ariwisi oriṣiriṣi jade, bi awọn kan ṣe n kin Baraka lẹyin pe, lootọ ni, Mosun Filani ṣe igberaga ju l’asiko yẹn, ni awọn kan n bu ẹnu atẹ lu pe, kii ṣe gbogbo nkan ni agbalagba maa n sọ.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search