Ijinigbe Ipinlẹ Ọyọ Ma Ti Da Wahala Nla Si’lẹ L’aarin Ṣeun Kuti ati VeryDarkMan, Ẹ Wa Gbọ Bi Wọn Ṣe N Ki Ipọnri Ara Wọn

Ijinigbe Ipinlẹ Ọyọ Da Wahala Nla Si'lẹ L'aarin Ṣeun Kuti ati VeryDarkMan

Gbajugbaja olorin, Ṣeun Kuti to tun jẹ ọmọ-bibi-inu Abami Ẹda Fẹla Anikulapo Kuti l’oun ati gbajumọ ori ayelujara to tun jẹ ajafẹtọ ti gbogbo aye mọ si VDM abi VeryDarkMan ni wọn ti gbe pẹrẹgi ija le naa gidi gan-an bayii. Ija awọn mejeeji yii ti wa fẹ di ọrọ “Orogun Adedigba.”

Ṣeun Kuti lo ṣe fọnran s’ori ayelujara to si n fi ọrọ ranṣẹ si VDM pe ko ma f’ọkan si pe ifẹhonuhan to le’waju rẹ wa si Ibadan nipinlẹ Ọyọ lo jẹ ki wọn ri awọn ti wọn jigbe nipinlẹ Ọyọ gba pada. Ṣeun ni ọgbọn buruku lati ri Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ lasan ni VDM fi iwọde naa ṣe, ti eyi ko si ni nnkan ṣe pẹlu bi wọn ti ṣe ri awọn ti wọn jigbe naa gba pada.

Ṣeun lo ta VDM l’aya pe ko ja’de wa sọ ohun kan ṣoṣo ninu awọn ohun to ti gbiyanju le l’ori to si ti gbọ ni orilẹ-ede Naijiria. Ṣeun ba tun tẹsiwaju pe bo jẹ pe lootọ ni VDM le ko awọn eniyan so’di lati ti dun’kooko mọ ijọba lati le ṣe oun ti wọn ba n fẹ, ki wọn o niṣo lọ f’ẹhonu han ki ijọba o le wa nnkan ṣe si airiṣẹ ṣe nitori ọpọlọpọ awọn alatẹle VDM ti wọn pe ni “Ratel” ṣugbọn ti Ṣeun pe wọn ni “Rat” iyẹn awọn eku wẹwẹ lo nilo iṣẹ ṣugbọn ti VDM ko wulẹ fẹ wọn fun ire ki wọn o ma ba m’ootọ.

Ko tan si’bẹ, Ṣeun tun fi ẹsun kan VDM pe arijẹ nidi ibajẹ lasalasan ni, nitori bi ilu o ba bajẹ, wọn o jẹ nnkan, ohun ti ilu yii ba si fi le da kia ni wọn yoo parẹ mọ’gba.

Ka to ṣẹju pẹ, gbajumọ l’ori ayelujara, Tunde Ednut t’awọn miiran tun pe ni ‘Olori Ọdọ’ lo ni ti gbe fọnran Ṣeun, labẹ fọnran yii gan-an laipẹ rara ni VDM ti da Ṣeun l’ohun, to si bẹrẹ si ni ka awọn aṣeyọri rẹ l’ọtun l’osi.

VDM ni ọpọlọpọ awọn to n ta’ja lai gba aṣẹ l’ọwọ ajọ NAFDAC l’oun ti gbogun ti, oun ran wọn l’ọwọ lati ṣi ọja kan ti wọn fẹ tipa nipinlẹ Anambra. Bẹẹ lo tun ni ifẹhonuhan awọn lo mu ki Minisita f’ọrọ olu-ilu orilẹ-ede Naijiria, Abuja iyẹn Nyesom Wike lati tete wa nnkan ṣe si idaṣẹsilẹ awọn olukọ nigba kan. Akaimọye iranwọ owo, ipese omi ati bẹẹ bẹẹ lọ, ko to wa d’ori ti ifẹhonuhan ipinlẹ Ọyọ. VDM ni Gomina mu da oun le l’oju pe ko ni to oṣu kan si igba naa t’awọn ọmọ naa yoo fi de. VDM ni ṣe ọrọ ko ri bẹẹ lootọ.

Kaluku ti ọrọ awọn mejeeji yii ka l’ara lo ti bẹrẹ si ni ṣe’gbe l’ẹyin ẹni ti ọrọ rẹ ba ta julọ l’eti wọn ninu awọn mejeeji.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search