Peller Ṣe Ikilọ Pataki F'awọn Ti O L'ero Igbeyawo Laarin Ọdun Yii Si Ọdun To N Bọ
Ikilọ pataki nla ma re ti gbajugbaja irawọ ori ikanni TikTok, Habeeb Hamzat ti gbogbo aye mọ si Peller fi si’ta f’awọn eeyan paapaa julọ awọn ti ko ni l’ọkan lati ṣe igbeyawo l’aarin ọdun yii si ọdun to n bọ. Ṣe ẹ kuku mọ pe Peller ti dajọ igbeyawo alarinrin sọna pẹlu iyawo rẹ Jarvis ni ọjọ kinni oṣu kẹjọ August 1st to ku diẹ.
Bakanna, gbajugbaja olorin rap ti ọpọ awọn eeyan mọ si Erigga na sin awọn ọkunrin ni gbẹrẹ ipakọ l’ori bi wọn ba fẹ bi’mọ abi bẹrẹ si ni ko ẹbi jọ.
Peller ni tiẹ lọ s’ọrọ l’asiko to wa l’ọdọ gbajumọ alafẹ ati olokoowo, Pascal Okechukwu ti gbogbo aye mọ si Cubana Chief Priest abi C.P lati lọ gbe aṣọ, nnkan-kan ati awọn ohun miiran fun-un, ko si tun fi iwe pe.
Ninu itakurọsọ wọn ni C.P ti n beere bọya Peller ṣetan lati wọ’nu igbeyawo lootọ nitori ohun ẹlẹgẹ gidi gan-an ni, ti oun ko si ni fẹ kopa ninu eto igbeyawo ti ko ni da’lẹ.
Panran ti Peller yoo f’esi, o ni ki C.P f’ọkan balẹ nitori oun ati Jarvis gan ti n gbe papọ bi l’ọkọ-l’aya fẹ kan tẹlẹ, ati pe ibi ti aye f’oju si, ọna kii ṣaba gba’bẹ, nitori iru igbeyawo awọn ti ọpọlọpọ n ṣe iyemeji l’ori rẹ gan-an lo ma wa n pada t’ọjọ, si iyalẹnu ọpọlọpọ.
Ninu ọrọ Peller lo tun ti sọ pe, ẹnikẹni ti ko ba ṣe igbeyawo l’ọdun yii, o wa pẹ tan ọdun to n bọ, koda ọdun to n bọ gan le pẹ, iru ẹni bẹẹ le ma ri obinrin gidi fẹ mọ l’aye Gen Z ta wa yii.
Ẹwẹ, ọrọ gbajugbaja olorin takasufe iyẹn “rapper” ti wọn pe ni Erigga, ori ayelujara lo ti tẹ ọrọ ranṣẹ, to si n gba awọn ọkunrin l’amọran pe botile wu ki owo wọn pọ to, wọn gbọdọ yago fun nini ọmọ pẹlu oriṣiriṣi obinrin, o ṣ’aleye pe ki awọn ọkunrin ma jẹ ki o ju obinrin kan lọ ti yoo bì’mọ fun wọn nitori bi owo a ti bukata wọn gan ba wa, ko le lailai di ipo wiwa ni’bẹ fawọn ọmọ gẹgẹ bii baba, alaafia ati iduroṣinṣin ile. Ọrọ nini ko le ra gbogbo awọn nnkan yẹn, ati pe oripa ẹda kii ṣe ni’pa iye ọmọ to bi, bi ko ṣe ni’pa iye ọmọ to ri tọ yanju.