Agbaojẹ oṣerekunrin, Richard Mofe Damijo ti gbogbo eeyan mọ si RMD lo ti ni bi oun ṣe ti pe ẹni ọdun marundinlaadọrin yii, o da bi ẹni pe afikun akoko l’oun n lo.
RMD lo sọ eyi nibi ifọrọwanilẹnuwo kan to ti n ṣalaye bi oun ṣe nifẹ si jijẹ ọmọ orilẹ-ede Naijiria ati idunnu rẹ pe o wa laye lati ri ọpọ awọn eeyan ti wọn n ni iṣẹ ọwọ l’asiko yii.
O ni idi ti oun fi maa n ro pe afikun asiko l’oun lo ni pe, awọn obi oun o pe ọgọta ọdun laye nitori rẹ, ọpẹ laye oun gba.
Nigba to n sọrọ lori aṣiri bo ṣe n kere si loju, o ni oun maa n jẹ ohun to tọ bẹẹ l’oun o kii fi ere idaraya ṣ’ere.
O fi kun pe oun maa n gbiyanju lati ma jẹ ki ọjọ ori to n lo lori oun han nipa iṣesi ati imura. O ni ọpọ awọn ẹgbẹ oun ni wọn o kii mura bi oun ṣe maa n mura nitori ọjọ ori.
Oṣere naa ni, akọbi oun to jẹ ọmọ ọdun mẹtalelogoji gan maa n wo oun t’oun ba ti mura, ko dẹ si l’ọkan oun lati yii pada.
RMD to jẹ ọkan gboogi laarin awọn onisinima agbelewo l’ede oyinbo lo bẹrẹ sinima ṣiṣe lori itage ni ọdun 1984 ko to bọ si agbọn sinima agbelewo. O ja gbangba ni ọdun 1997 to si n ṣe daadaa di oni.