Gbajugbaja arẹwa oṣere tiata, Tọpẹ Ọṣọba to ja’de l’aye laipẹ yii, eleyi ti iroyin iku rẹ kan ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ ni eewo ni ọrọ tun ti ba ibomiran yọ l’ori ọrọ iku rẹ.
Ẹ ranti pe nnkan bi ọdun meji sẹyin ni arẹwa oṣerebinrin naa ra’wọ ẹbẹ s’awọn ọmọ Naijiria fun iranwọ owo l’ori aisan jẹjẹrẹ to n ba fa l’asiko naa.
Eyi gan-an ni ọpọ l’ero pe o ṣ’okunfa iku to pa Tọpẹ Ọṣọba, ẹni to ja’de l’aye ni ogoji ọdun. Amọ ṣa, ọjọ diẹ l’ẹyin ipapoda oṣerebinrin naa, awọn mọlẹbi rẹ ti fi ọrọ si’ta.
Ninu atẹjade ti wọn fi le’de ni wọn ti ṣalaye pe o jẹ ohun to pa kun ibanujẹ awọn pe iroyin ti ko fi’di mu’lẹ n’ipa ohun to pa ọmọ awọn l’awọn aye n gbe kiri.
Wọn tan imọlẹ si pe jẹjẹrẹ bi ọpọ ti l’ero, ti wọn si n gbe kiri kọ lo pa ọmọ awọn. Nipa koko ohun to pa Tọpẹ Ọṣọba, wọn ni bo ba di ni ọjọ iwaju ti ko ni pẹ pupọ, awọn yoo ma tan imọlẹ si ọrọ naa siwaju si ṣugbọn l’ọwọ yii, k’awọn alariirisọ d’ẹkun ati mọ pe jẹjẹrẹ lo pa ọmọ awọn.