Agbo Mi To F’ẹyin Rin, O N Mu Agbara Bọ – Broda Shaggi

Adẹrinpoṣonu ati oṣerekunrin, Samuel Perry ti gbogbo eeyan mọ si Broda Shaggi lo ti sọrọ lẹyin ọpọlọpọ oṣu ti iroyin gbe pe wọn yin’bọn fun ni ibi to ti n ya iṣẹ fiimu nipinlẹ Ogun.

Ninu atẹjade kan to fi s’ori agbagbe WhatsApp rẹ, Shaggi dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ fun aduroti wọn nigba t’oun o si ni’le.

O ni lootọ oun o ti raye ba wọn ṣe daadaa bi oun ṣe fẹ ṣugbọn aduroti wọn ti ran oun lọwọ l’asiko t’oun n k’oju ipenija yii.

Shaggi ni oun o ti le sọ gbogbo nkan t’oju oun ri bayi ṣugbọn ki awọn ololufẹ oun ni l’ọkan pe oun o gbagbe wọn.

O fi kun pe laipẹ, oun maa padà s’ori ayelujara pẹlu agbara ọtun, t’oun si ni ireti pe ọjọ naa o ni pẹ mọ. O wa dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ lẹẹkan si fun suuru wọn ati aduroti.

Broda Shaggi ni o ṣeṣe nibi to ti n ya iṣẹ fiimu kan ni agbegbe afara Sango Ota nipinlẹ Ogun. Lẹyin iṣẹlẹ naa ni adẹrinpoṣonu naa ti fi ori ayelujara silẹ ti ọpọ awọn ololufẹ si n reti igba ti yoo pada.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search