Alaga ajọ to n risi pipawo s’apo ijọba, Nigeria Revenue Service (NRS), Zacch Adedeji ti kọ iroyin pe awọn ti wọn wa l’agbọn ijọba n gbe igbe-aye fami-lete-ki-n–tọ. O ni koda Aarẹ Tinubu o gbe igbe-aye karimi pẹlu ipo to wa.
O sọ eyi nibi ifọrọwanilẹnuwo kan lori ẹrọ amohunmaworan ti wọn ti bi nipa igbe-aye awọn ti wọn wa nijọba pẹlu gbogbo ni nkan o ṣe ṣ’ẹnu ire pẹlu ọrọ aje ilẹ wa.
Ọrọ yii lo jẹyọ pẹlu bi ọpọlọpọ ariwisi ti ṣe n tẹle owo ti ijọba n na ati bi awọn ti wọn wa ni ijọba ṣe n jaye olowo nla pẹlu bi nkan ṣe nira fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria.
Nigba to n dahun ibeere lori irin Aarẹ ati iroyin awọn ọkọ bọginni, Adedeji ni Aarẹ Tinubu maa n f’ẹsẹ rin lati ile lo si ibi-iṣẹ ni, koda, igba to ba n lọ si papa ọkọ ofurufu nikan lo maa n gbe ọkọ.
O tẹsiwaju pe, Aarẹ kii jẹun ju ẹkan pere lọ l’ojumọ bẹẹ ni ko tii kuro l’orile-ẹde Naijiria lati oṣu mẹta sẹyin.
Adedeji ni, elo ni ọkọ bọginni Escalade ti odidi Aarẹ orilẹ-ede Naijiria o le ra. O ni bi eeyan ba de ọdọ Aarẹ bayi, ori iṣẹ ni wọn maa ti ba.
O wa beere pe igba wo ni awọn eeyan ti ri nibi ayẹyẹ gbẹyin tabi ti wọn ri pe o lọ fun isinmi tabi nibo mii.
Ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti bu ẹnu atẹ iye owo ti orilẹ-ede Naijiria n na lori iṣejọba l’ọdọọdun.