A Ṣe Agọ Ọlọpa Ni Tọpẹ Ọṣọba Ku Si, Ẹ Wa Gbọ Aṣiri Nla Ti Ọkọ Rẹ Tu Ati Bo Ti Ṣe Kan Baba Olowo, Mike Adenuga

Iroyin iku to pa gbajugbaja oṣere, Tọpẹ Ọṣọba lo ti wa da bi egberin ọtẹ bayii, ba ti n pa’kan ni’kan n ru. N ṣe oriṣiriṣi awọn aṣiri kan n ṣubu le’rawọn l’ori ọrọ naa.

Ṣẹ ẹ kuku ranti pe l’ẹyin ipapoda arẹwa oṣerebinrin yii ni ẹni ogoji ọdun (40 years) ni awọn mọlẹbi rẹ ja’de lati ṣe alaye pe ko dun mọ awọn ninu pe iroyin pe aisan jẹjẹrẹ ọyan ti Tọpẹ Ọṣọba ba fin’ra ni’bi ọdun meji sẹyin, t’awọn aye fi na’wọ iranwọ si lo pa ọmọ awọn, ti awọn mọlẹbi rẹ si pe ibi aye f’oju si, ọna o gba ibẹ lọ rara ṣugbọn ti wọn ko sọ ni pato ohun to ṣokunfa iku oṣerebinrin naa.

Wayii, ọkọ-afẹsọna Tọpẹ Ọṣọba, Wooli Itunu Ọnadẹkọ fun’ra rẹ lo ti ja’de s’aye lati wa tu aṣiri ikọkọ l’ori iku to pa oṣerebinrin yii.

Ọnadẹkọ ni aagọ ọlọpa kan ni Ikorodu ni’pinlẹ Eko ni Tọpẹ Ọṣọba ku si.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ile-iṣẹ iroyin atọpinpin kan ti wọn n pe ni Celestial Reality Check to tan mọ ijọ mimọ Celestial Church of Christ ni Ọnadẹkọ ti ṣalaye awọn ọrọ yii l’ọjọ Abamẹta Satide anaa.

Wooli naa to tun jẹ afẹsọna rẹ ni kosi ohun to jọ pe Tọpẹ Ọṣọba ku l’at’ari aisan jẹjẹrẹ, abi jijẹ majele, abi bi boya wọn fi iya jẹ d’oju iku.

 

O ṣ’alaye siwaju si pe ṣadede enikan ti oun ko mọ pe oun, ni aago mejila l’ọganjọ oru pe Ọṣọba ti ku si agọ ọlọpa ni Ikorodu.

O tẹsiwaju pe, bi oun ko ti ẹ mọ agọ ọlọpa to jẹ ni pato, n ṣe ni ohun tete gba agọ ọlọpa to sunmọ ohun julọ lati lọ fi to wọn l’eti.

Ọnadẹkọ tun fi kun pe, asiko diẹ ṣaaju ipapoda oṣere yii, ni Ọṣọba t’ẹnumọ p’oun fẹ lọ ri ẹnikan to n jẹ  Kehinde Ọṣọba, t’oun naa ni ijọ. O ni, Ọṣọba ati onidiri kan ti Ọṣọba n gbe lọdọ rẹ ni wọn jọ lọ si’bẹ ṣugbọn ti oun ko r’aaye tẹle wọn nitori iṣẹ ijọ to pọ l’ọwọ oun ni’gba naa, ti oun kan fi Ọlọhun sin wọn, ti awọn si tun s’ọrọ pọ. Koda Ọṣọba tẹ ọrọ kan s’ori ayelujara to kọ bayii pe “Ogo Tuntun”.

O fi kun pe, Ọṣọba sọ f’oun pe oun fẹ ri l’awọn asiko naa amọ ṣa ti iṣẹ ijọ ko ti gba ohun l’aaye.

O wa ṣe adayanri rẹ pe ahesọ lasan ni ọrọ kan to n lọ ni’gboro pe ọgbọn miliọnu naira t’awọn eeyan, to fi mọ gbajumọ bọrọkini, Mike Adenuga da fun Ọṣọba ni’gba ti aisan jẹjẹrẹ n ba fin’ra ni oun fi kọ ijọ oun.

O tan imọlẹ si pe, ti ijọ oun ti n bẹ lati bi ogun ọdun sẹyin, to si jẹ pe bi ọdun meji sẹyin pere ni oun ati Ọṣọba mọ’ra. To ja si pe ṣọọṣi oun si ti duro tam ki Ọṣọba o to da’ra pọ.

Gbogbo ọrọ ti Ọnadẹkọ afẹsọna Ọṣọba sọ yii lo mọ ninu ifọrọwọrọ to ṣe ti ko si ti si ẹri to da yatọ to gbe e l’ẹsẹ abi tako.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search