Ere Asalatu L’oun O Fi Islam Silẹ Lẹyin To Pa Orukọ Da Si Ere Cele

Gbajugbaja onkọrin ẹsin Islam, Alh. Abd. Kabir Bukola Alayande ti gbogbo eeyan mọ si Ere Asalatu lo ti pada sọrọ lori ariyanjiyan to bẹ silẹ lori ayelujara laarin awọn ẹlẹsin lẹyin to lọ ṣ’ere ni ijọ Cele kan.

Nibi ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu gbajugbaja oṣerebinrin, Biola Adebayo lo ti fidi rẹ mulẹ pe ko si nkan to ṣe ẹsin oun o nitori musulumi ododo l’oun, bẹẹ lo bu ẹnu atẹ lu awọn ti wọn n ṣiye meji lori ẹsin rẹ gẹgẹ bi musulumi.

Ere Asalatu ni ere t’oun ṣe ni ijọ Cele naa o ni nkankan ṣe pẹlu ẹsin oun rara. O ni musulumi l’oun t’oun si n ṣe awọn opo Islam maraarun-un, ko da gbogbo awọn ọmọ oun ni wọn ni orukọ musulumi.

 

Onkọrin naa ni awọn ti wọn ba ni Islam o f’ọwọ si orin kikọ o tii ka Qur’an wọn pe. O ni ni lootọ ni Qur’an ṣ’epe  fun awọn olorin ṣugbọn afikun wa pe ayafi awọn ti wọn ba kọ orin pẹlu ibẹru Ọlọhun.

O beere lọwọ awọn ti wọn n bu ẹnu atẹ lu pe ṣe oun kọrin bu iya wọn abi oun kọrin pe ko si Ọlọhun.

Ere Asalatu ni ọpọ awọn eeyan bu ẹnu atẹ lu lo lori ere to lọ ṣe ni ijọ Cele kan ti wọn si ni kii ṣe musulumi ododo. Lẹyin naa ni lo sọ ara rẹ l’orukọ Ere Cele.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search