Gbajugbaja alawada to tun jẹ ogbontarigi ati agbaojẹ oṣere ni’lẹ yii, Ọjọgbọn Afeez Oyetoro ti gbogbo aye mọ si Saka lo ti wa t’oju onika mẹsan ka nipa irufẹ eeyan ti gbajugbaja oṣere ati agbesimimajade, Funkẹ Akindele ti gbogbo aye mọ si Jẹnifa jẹ.
Ọrọ ti Saka sọ yii ni’pa Jẹnifa lo jẹ ja jade l’asiko ti Saka n dahun ibeere kan ti wọn bi l’ori eto Podcast kan pe wọn ni Funkẹ Akindele buru gan-an ni bi wọn ba n ṣiṣẹ l’ọwọ, ti oju rẹ a si mọ k’ọrẹ l’ọwọ to n ṣ’apẹrẹ pe gbajumọ oṣere naa roro pupọ.
Saka ṣ’ẹri ọrọ naa pe otito ni ṣugbọn to jẹ pe oun bii ẹnikan f’ara mọ, ti oun ko si ri laifi kankan ninu iṣesi ati ihuwasi Jẹnifa.
O ṣalaye pe ko le e mọ ri bẹẹ nitori bi ọrọ iṣẹ wọn ti gba niyẹn. O ni, ojubọọrọ kọ la fi n gba ọmọ l’ọwọ ekuro. Iṣẹ to jẹ pe obitibiti miliọnu naira ni yoo pari rẹ ko ṣe mu ni imu yọbọkẹ, afi ki eniyan fi ara balẹ daadaa lati ṣe oun gbogbo l’eto leto.
O ni ilana alagbajọwọ ni iṣẹ awọn gba, de’bi pe bi iṣẹ ẹnikan ba mẹhe, o le e ba gbogbo iṣẹ jẹ lodidi.
Saka wa yan pe ni iwoye t’oun ati pẹlu ibaṣepọ t’awọn ti jọ ni, Funkẹ Akindele kii ṣe eeyan to buru o, ayafi bi eniyan fun’ra rẹ ba jẹ lmẹlẹ, to ya ọlẹ to n fi iṣẹ se’re nikan lo ma pe Funkẹ buru mọ oun, ti oun ko si ri laifi ni’bẹ nitori oninkan o ni fẹ ko bajẹ. Funkẹ o fẹ palapala rara. O mu iṣẹ rẹ lokunkundun pupọ.
Saka tẹsiwaju pe, Funkẹ jẹ alaanu ẹda, onírẹlẹ ati ẹni to ni aajo, to dẹ ma n karamasiki ọmọlakeji de’bi pe bi ohunkohun ba ṣe ẹnikẹni l’asiko t’awọn ba wa lẹ’nu iṣẹ, kiakia Funkẹ a ti dide si onitọhun lati ṣe aajo rẹ.
Lakotan Saka ni Funkẹ o buru rara, iṣẹ rẹ lo mu lokunkundun, t’oun ko si ri aburu kankan ni’bẹ oun tun fi gba ti ẹ si ni. Saka ẹni to ti kopa to jọ’ju ninu oriṣiriṣi iṣẹ lat’ọwọ Funkẹ Akindele.