Lai Lai Ko Le Ṣẹlẹ! Kiekie L’oun O Le B’awọn To N Fi Kiki Ọyan ati Idi Ṣe Kọntẹnti Wọn Ṣe

Lai Lai Ko Le Ṣẹlẹ! Kiekie L'oun O Le B'awọn To N Fi Kiki Ọyan ati Idi Ṣe Kọntẹnti Wọn Ṣe

Gbajugbaja agbefọnranjade l’ori ayelujara, Bukunmi Adeaga Ilọri ti ọpọ awọn eniyan mọ si Kiekie lo ma ti s’ọrọ.  O ni bo ba ṣe pe t’oun ni, gbogbo awọn akẹgbẹ oun t’awọn jọ n fi fọnran s’ori ayelujara kọ ni oun le ba ṣiṣẹ pọ.

Kiekie lo s’ọrọ yii l’ori eto onifọrọwerọ iyẹn (podcast interview) to ti kopa laipẹ yii gẹgẹ bii alejo. Ninu rẹ ni Kiekie ti la ọrọ mọ’lẹ pe o l’oju awọn t’oun le ba ṣe fọnran abi ‘kọntẹnti’ papọ paapaa julọ bo ba ti jẹ pe kiki aṣa-kaṣa, awọn nnkan palapala, to jẹ pe iru ẹni bẹẹ ko mọ ju ọrọ ọyan abo abi ibadi. Kiekie pe ni t’oun o, awọn o le jọ ṣe.

 

Lo ba tun tan’mọlẹ si pe oun ko pe oun ti wọn ṣe o dara o, koda oun ko ni iṣoro kankan pẹlu wọn, bẹẹ si ni oun ko f’oju kere abi pa iṣẹ wọn rẹ. Amọ ṣa oun to yẹ’ni lo yẹ’ni. Okun-ọrun ko yẹ adiyẹ. Irufẹ awọn fọnran bẹẹ ko ṣ’apọnle ohun ti oun gbe dani ati oju ti awọn alatẹle oun fi n wo oun.

Ẹwẹ, nigba ti atọkun naa bi Kiekie l’eere pe ko tọka si iru awọn to n sọ. Kiekie gbiyanju ati ranti ṣugbọn to pada ni orukọ kankan ko wa si oun l’ori l’asiko naa ṣugbọn to daju pe oun ti wo, ti oun si mọ awọn agbefọnranjade l’ori ayelujara kọọkan to jẹ pe kobo-kobo ati palapala lo pọ ju ninu iran wọn.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search