Ariwo Sọ Ni’pinlẹ Ọṣun, Gomina Adeleke Onijo Wọ’le Saa Keji

Lẹyin ọpọ oṣu ti ipolongo ibo fi wa’ye, eto idibo pada tẹle l’ana ode yii ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹjọ ọdun 2026 ni’pinlẹ Ọṣun, kinni naa le pupọ de’bi pe ibo ipinlẹ Ọṣun nikan mi gbogbo orilẹ-ede Naijiria titi.

Lopin ohun gbogbo, ka-wi-ka-fọ, ka-fọ-ka-wi, ajọ INEC kede esi idibo ipinlẹ Ọsun ni kutuhai oni, ọjọ Aiku (Sunday) ọjọ kẹrindilogun oṣu kẹjọ ọdun 2026 ni nnkan aago meje aabọ owurọ ku iṣẹju perete.

Nibamu pẹlu ikede Giwa fasiti Oyẹ Ekiti, Ọjọgbọn Joshua Oguwọle, ẹni to wa ni’po lati kede esi ibo naa, o ṣalaye pe lẹyin apapọ akojọpọ gbogbo ibo, Gomina Ademọla Adeleke Jackson ti inu ẹgbẹ oṣelu Accord lo gbe igba oroke, to si wọ’le idibo naa pẹlu ibo to le belenja ni ẹgbẹrun l’ọna ẹẹdẹgbẹta (511,067), ti Ogunwolẹ si da Adeleke pada gẹgẹ bii olubori Oludije, to ja si saa keji Gomina Adeleke l’Ọṣun.

Ijọba ibilẹ mọkandinlogun (19) ninu ọgbọn (30) Adeleke ti bori, Ariwa Ẹdẹ, Guusu Ẹdẹ, Ejigbo, Iwo, Ẹgbẹdọrẹ, Ariwa Ifẹ, Ila-oorun Ifẹ, Aaringbungbun Ifẹ, Oriade, Ifẹlodun, Orolu, Ayedaade, Ayedire, Odo Ọtin, Boluwaduro, Iwọoorun Ileṣa, Ifẹdayo, Oṣogbo ati Ayedire.

Bọla Oyebamiji ti inu ẹgbẹ oṣelu APC to ṣe ipo keji pẹlu ibo ẹgbẹrun l’ọna irinwo le ni merinlelogoji le belenja (444,815), lo wọ’le ni ijọba ibilẹ mọkanla to ṣẹ ku, Irewọle, Iṣọkan, Ọlọrunda, Ila-oorun Atakumọsa, Iwọ-oorun Atakumosa, Ila-oorun Ileṣa, Boripẹ, Irepọdun ati Obokun.

Ẹwẹ, ọmọ oye ẹgbẹ oṣelu ADC to tun jẹ abẹnugan ile-aṣofin lo ṣe ipo kẹta pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹtadinlogun o le belenja (17,180) ti awọn ọmọ oye ẹgbẹ oṣelu mẹtala to ku naa si ni iwọnba ibo wọn.

Gomina Adeleke ẹni ti ko le pa idunnu rẹ mọ’ra bi ibatan rẹ Davido lo fi ijo bẹẹ, to si tun mu orin ọpẹ bọ ẹnu fun aṣeyọri naa. Awọn mọlẹbi, alajọṣe, alatẹle, ọmọ ẹgbẹ ati ọgọrọ awọn miiran lo ti n ranṣẹ ikini ku oriire si Gomina Adeleke, ẹni t’oun naa dupẹ l’ọwọ Aarẹ Bọla Tinubu to f’aaye gba ki eto idibo naa o kẹsẹjari, to si tun ni oun n na’wọ ifẹ ati ibaṣepọ si awọn ti ibo naa ko ja mọ l’ọwọ, to si pe oun n reti ki wọn ki oun ku oriire.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search