Ọpẹlọpẹ MC Oluọmọ, Mi O Ba Ti D’oku – Ronkẹ Oshodi Oke

Ọpẹlọpẹ MC Oluọmọ, Mi O Ba Ti D'oku - Ronkẹ Oshodi Oke

Gbajumọ oṣere tiata, Ronkẹ Ojo ti ọpọ mọ si Ronkẹ Oshodi Oke lo ma ti t’ẹnu bọ itan ti ọpọ awọn eeyan, koda to fi mọ awọn ololufẹ rẹ ko gbọ ri ni’pa rẹ.

Oshodi Oke lo s’ọrọ laipẹ yii pe oun i ba ti ku ti pẹ, ọpẹlọpẹ Ọlọhun to gbe ẹmi oun ro, to si fi gbajumọ ọga ọlọkọ l’Eko, to tun jẹ aarẹ fun ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW ni Naijiria l’asiko yii, Musiliu Akinsanya ti gbogbo aye mọ si MC Oluọmọ

ṣe gaari tira iyẹn onisababi oun.

 

Ninu ọrọ ti Oshodi Oke sọ, o ni aarẹ nla kan kọlu oun ri to jẹ pe kinni naa le pupọ ju, to si tun jẹ aisan run’wo-run’wo. O ni bii oogun t’owo rẹ to ẹgbẹrun l’ọna ẹgbẹrin naira (#800,000) l’oṣu ni oun ma n lo. O ni ọpẹlọpẹ MC Oluọmọ l’ara oun ati iranlọwọ awọn oṣere akẹgbẹ oun kọọkan, lo ba darukọ arẹwa irawọ oṣere, Ṣotayọ Gaga.

Oshodi Oke ni oun ma n ṣọra gidi lati darukọ awọn akẹgbẹ rẹ ṣugbọn oun gbudọ darukọ Ṣotayọ nitori oun ko l’ero rẹ rara nitori aawọ kekere kan ti wa l’aarin awọn mejeeji ṣaaju ṣugbọn ti Ṣotayọ f’owo ran oun l’ọwọ pẹlu ẹgbẹrun l’ọna aadọjọ naira (#150,000). Ni gba ti wọn tun bii boya oun ati Ṣotayọ ti n s’ọrọ pada, o ni koda awọn a kan gb’oju s’ẹgbẹ ni b’awọn ba pade ara awọn l’ode ariya.

Ni kukuru ede, Ronkẹ Oshodi jẹwọ oore ti Ọlọhun ni ko ri gba l’ọwọ MC Oluọmọ ati awọn oṣere akẹgbẹ rẹ bii Ṣotayọ Gaga.

 

Popular Yoruba actress Olaide Oyedeji, who has been based abroad for several years, has advised women against undergoing Brazilian Butt Lift (BBL) procedures simply to attract men or gain financial attention.

In a video shared online, the actress urged women considering butt enhancement to learn from her experience. She warned that increasing one’s physical appearance with the expectation that men would suddenly become more interested or spend more money on them could lead to disappointment.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search