Ọpọ Awọn Eeyan Ma N Ro Pe Orukọ Baba Mi Lo N Gbe Mi – Temi Kosoko

Oṣerebinrin to jẹ ọmọ gbajugbaja oṣere nni Jide Kosoko, Temi Kosoko ti sọrọ lori bi ọpọ awọn eeyan ṣe ro pe ọla baba rẹ lọ fi n mi ati pe ti ko ba si orukọ baba rẹ ko le jẹ nkankan.

Temi lo sọ eyi di mimọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan ti fọnran ẹ n kaakiri bayi to ti sọ pe ọpọ awọn eeyan maa n sọ pe ti baba oun ba ti k’owo kalẹ l’oun maa n ṣe sinima jade. Ninu fọnran naa lo ti sọ pe ọpọ awọn eeyan ni wọn maa n ro pe baba oun lo n ran oun lọwọ ṣugbọn ko ri bẹẹ. O ni lootọ baba awọn n gbiyanju ṣugbọn mẹtala ni gbogbo awọn nitori bẹẹ ko ṣeeṣe ko gbe gbogbo bukata oun. O fikun pe lootọ o, orukọ baba oun ṣe iranwọ fun oun

Oṣerebinrin naa sọrọ nipa bi ọpọ awọn eeyan ṣe maa n lero pe oun ni igberaga nitori baba oun lai tiẹ gbọ ọrọ ẹnu oun rara.

O ṣalaye pe ni gba t’oun ṣi wa n’ile-iwe gan pẹlu bi oun ṣe maa n ṣe daadaa ninu ere ori itage t’oun fi gba ami ẹyẹ lẹẹmẹta ọtọọtọ, ọpọ awọn ẹgbẹ oun ni wọn maa n sọ pe tori baba oun ni wọn ṣe maa n fun oun.

O tẹsiwaju pe koda ninu agodo tiata awọn ẹlomii a f’ẹjọ sun baba oun pe oun ni gberaga ti ko dẹ ri bẹẹ.

Temi Kosoko lo jẹ abigbẹyin gbajugbaja oṣere tiata nni, Jide Kosoko ati oloogbe Henrietta Kosoko.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search