O n jọ pe ọrọ ifẹ aarin agba onkọrin Innocent Idibia ti gbogbo eeyan mọ si 2Baba ati iyawo rẹ to fẹ laipẹ yii, Natasha Osawaru to jẹ aṣofin nipinlẹ Edo ti d’opin.
Eyi o ṣẹyin bi aṣofin naa ṣe yọ ara rẹ kuro lara awọn ti wọn n tẹle onkọrin naa lori itakun ibanidọrẹ Instagram, eyi to fa ti ọpọ fi ro pe ina ifẹ wọn to n jo tẹlẹ ti ku.
Ṣaaju akoko yii, 2Baba lo ti kọkọ yọ ara rẹ kuro lara awọn ọrẹ Natasha lẹyin ti ija itagbangba bẹ lẹ laarin awọn mejeeji ni kilọbu kan l’ọjọ keje oṣu to kọja.
Ni ọjọ kọkandinlogun oṣu yii ni 2Baba ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi mokanlelaadọta (51), nibi eyi ti fọnran ti ṣafihan awọn ọmọ rẹ, iya rẹ ati awọn mọlẹbi ṣugbọn Natasha to jẹ iyawo rẹ o si nibi ayẹyẹ naa.
Awọn iṣẹlẹ yii lo ni ṣafihan pe nkan o ṣ’ẹnure laarin awọn ololufẹ mejeeji naa.
Bi o tilẹ jẹ pe wọn o kii ṣe ọrẹ mọ lori ayelujara, Natasha o tii yọ orukọ Idibia kuro ninu orukọ rẹ lori itakun ibanidọrẹ Instagram.
Ẹ ṣe’ranti pe 2Baba ati Natasha fi ọrọ ifẹ han de lẹyin igbeyawo wọn ninu oṣu keje ọdun 2025, lẹyin ti 2Baba kede pe oun ati iyawo rẹ tẹlẹ Annie Idibia ti kọ ara wọn.
Igbeyawo wọn fa ọpọ rogbodiyan paapaa julọ bi awọn idile 2Baba ṣe kọ lati gba Natasha wọle gẹgẹ bi iyawo.
Ọpọ ariwisi lo ti jẹyọ lori ayelujara bayii nipa awọn mejeeji ti awọn kan si ni paṣan ta fi na iyale ti n ba iyawo naa.