O Ma Ṣe O, Igi Nla Wo L’agboole Tiata, Olu Jacobs Ti Ku

O Ma Ṣe O, Igi Nla Wo L'agboole Tiata, Olu Jacobs Ti Ku

Eerin ti wo, ajanaku ti sun bi oke, ogbontarigi oṣere, to jẹ ọkan ninu awọn iwọnba alalẹ ere tiata to ṣẹku l’orilẹ-ede Naijiria ti papoda. Baba Oludọtun Baiyewu Jacobs ti gbogbo aye mọ sanpọna si Olu Jacobs ti dagbere f’aye.

Olu Jacobs lo mi eemi igbẹyin ni kutuhai oni, Ọjọru (Wednesday), ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan, ọdun 2026 gẹgẹ bii ọmọ ojimmi oṣere to n jẹ Olusọji Jacobs ṣe fi iroyin naa si’ta l’oni l’ori atẹ Instagram pe iroko ti wo, Olu Jacobs ti pa’ju de ni ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin (84).

Olusọji kọ bayii pe “Pẹlu ọkan ọpẹ si Oluwa fun igbesiaye rere, a kede ipapoda ọkọ wa ọwọn, baba, baba-baba ati ẹgbọn agba. Kinihun Lufodo fun’ra rẹ.”

O wa tẹsiwaju lati fi Ikilọ le ọrọ f’awọn onibulọga isọnu, iyẹn awọn oniroyin pajawiri onisọnu lati fi ọwọ wọ mọlẹbi awọn l’ori iṣẹlẹ yii l’asiko yii. Ki wọn ma t’ọwọ bọ ọrọ awọn l’oju.

Baba Olu Jacobs nigba aye rẹ lo jẹ akọni ati ogbontagi oṣere, agbesinimajade ati eekan ti o ṣe kọ iyan rẹ lai fi ewe nla rabata bo l’agboole awọn onitiata.

Okiki Olu Jacobs kan lati Naijiria, kaari ilẹ adulawọ, titi de ọdọ awọn eebo alawọ funfun, to si kopa ninu sinima wọn daadaa. Akaimọye l’awọn ami-ẹyẹ to jọ’ju ti irumọlẹ idi iṣẹ tiata to di oloogbe yii ti gba nigba aye rẹ. Pataki ninu awọn to gbẹyin baba Olu Jacobs ni aya rẹ t’oun naa jẹ ogbontarigi oṣere, Ajọkẹ Silva to ti ni tọju baba yii lati igba ti aisan ogbo ti de si, to ko to pada wa fi adagba eto rọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search