“Ẹẹmẹta loyun bajẹ lara mi, lawọn dokita ba sọ pe…” – Dayọ Amusa

Dayọ Amusa ni ọkọ oun nigba yẹn ti le lọmọ ogoji ọdun, o dẹ loun ko le ni suuru de igba t’Ọlọrun maa to da emi lohun, o ni ki n jẹ koun gbiyanju obinrin mi-in wo nita na, boya adura aa gba, o ṣetan ori ọmọ lo n pe ọmọ waye, eyi lọkunrin naa fi lọọ fun ẹlomi-in loyun, to si ba tiẹ lọ.

Dayọ tun ni laaarin kan, ile aye su oun patapata, ko tiẹ si nnkan to wu oun mọ, gbogbo nnkan lo run soun, tori ẹ niṣe loun maa n da nikan wa, toun aa kan maa wo suu lọpọ igba, atawọn ọrẹ oun ati mọlẹbi loun pa ti, iṣẹ tiata toun n ṣe paapaa, oun kọyin si i, nigba toun ko mọ nnkan toun iba tun ṣe.

Ṣa o, oṣere to ri rumurumu yii sọ pe oun ko le gbagbe isapa mama oun lori oun ni gbogbo asiko toun fi wa lagan naa, o ni ọpẹlọpẹ mama oun lara oun, ti wọn n gba oun lamọran, ti wọn si duro ti oun pẹkipẹki bii iṣan ọrun. Koda, o ni amọran mama oun ọhun eyi toun tẹle lọdun 2021 lo yi aye oun pada toun fi waa di ọlọmọ laye bayii.  

Lẹyin eyi lobinrin naa dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ rẹ, to si ki wọn kuu ọdun tuntun.

Obinrin bọrọkọtọ bii ọka, gbajumọ oṣere tiata ilẹ wa ti gbogbo aye ki kuu ewu ọmọ tuntun akọbi rẹ lọdun to kọja yii, Abilekọ Dayọ Amusa, ti ṣalaye ohun toju rẹ ri ni gbogbo asiko to fi wa nipo ambẹlọrun, o ni ẹẹmẹta ọtọọtọ loyun bajẹ lara oun, ti ibanujẹ nla si gba ọkan oun, ati pe laaarin asiko naa, awọn

dokita ni koun jẹ ki wọn ba oun fi iṣẹ abẹ gbe ile ọlẹ oun jade, ọkọ oun si tun fi oun silẹ lọọ fun ẹlomi-in loyun.

Gbogbo alaye yii lo wa ninu ẹkunrẹrẹ ọrọ kan ti Dayọ Amusa fi sọ bi ipenija to la kọja lasiko ti ko rọmọ bi, eyi to gbe soju opo ayelujara laṣalẹ ọjọ aisun ọdun tuntun, iyẹn ọjọ

kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2024 to kọja yii.

Loju opo instagiraamu rẹ, Mama ikoko naa ṣalaye pe ko si ohun meji to jẹ idaniyan ọkan oun ju bi oun ṣe maa jẹ obinrin ti igbe aye rẹ pe, toun naa maa ṣe nnkan tawọn ẹlẹgbẹ oun n ṣe, bii ki wọn ṣa fi orukọ ọmọ kan pe oun naa.

Screenshot_20250111-075909

Ninu apilẹkọ to pe akọle rẹ ni Ẹri aye mi (My Testimony) Dayọ Amusa ni: lẹyin ti oyun ti bajẹ lara mi lẹẹmẹta ọtọọtọ, lọdun 2015, esi ayẹwo kan fihan pe mo ni arun kan ni ile ọmọ mi, ti wọn n pe ni uterine myxomatosis, awọn dokita si sọ fun mi pe afi kawọn yọ ile ọmọ mi jade latari irora nla ati aifararọ ti mo n ni lasiko ti nnkan oṣu mi ba fẹẹ wa, amọ mi o gba pẹlu wọn o. Mo sa n lo oogun, abẹrẹ atawọn itọju oriṣiiriṣii ki ile ọmọ mi ma lọọ bajẹ, lẹyin eyi ni mọlẹbi mi kan gba mi lamọran lati waa fun itọju lorileede United Kingdom.”

Obinrin naa tun ṣalaye pe oun ṣiṣẹ abẹ kan lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Keji ọdun 2015, lati yọ kinni kan to n hu sinu ile ọmọ oun, TCRE Laparoscopy dye ni wọn n pe iṣẹ abẹ ọhun, sibẹ oyun kọ ko duro.

Nigba to ṣe, o loun atọkọ oun tun pinnu pe boya ki awọn lo ọna igbalode ti awọn obinrin fi maa n loyun nipasẹ ẹrọ ati imọ ijinlẹ, eyi ti wọn n pe ni IVF ni ikekuru lede gẹẹsi, gbogbo eyi lo lawọn gbiyanju ẹ leralera lọdun 2019 to jẹ pe pabo naa ni isapa wọn n ja si.

Dayọ Amusa
Ọmọ Dayọ Amusa jojolo

Dayọ Amusa ni ọkọ oun nigba yẹn ti le lọmọ ogoji ọdun, o dẹ loun ko le ni suuru de igba t’Ọlọrun maa to da emi lohun, o ni ki n jẹ koun gbiyanju obinrin mi-in wo nita na, boya adura aa gba, o ṣetan ori ọmọ lo n pe ọmọ waye, eyi lọkunrin naa fi lọọ fun ẹlomi-in loyun, to si ba tiẹ lọ.

Dayọ tun ni laaarin kan, ile aye su oun patapata, ko tiẹ si nnkan to wu oun mọ, gbogbo nnkan lo run soun, tori ẹ niṣe loun maa n da nikan wa, toun aa kan maa wo suu lọpọ igba, atawọn ọrẹ oun ati mọlẹbi loun pa ti, iṣẹ tiata toun n ṣe paapaa, oun kọyin si i, nigba toun ko mọ nnkan toun iba tun ṣe.

Ṣa o, oṣere to ri rumurumu yii sọ pe oun ko le gbagbe isapa mama oun lori oun ni gbogbo asiko toun fi wa lagan naa, o ni ọpẹlọpẹ mama oun lara oun, ti wọn n gba oun lamọran, ti wọn si duro ti oun pẹkipẹki bii iṣan ọrun. Koda, o ni amọran mama oun ọhun eyi toun tẹle lọdun 2021 lo yi aye oun pada toun fi waa di ọlọmọ laye bayii.  

Lẹyin eyi l’obinrin naa dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ rẹ, to si ki wọn ku ọdun tuntun.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search