Mo kabaamọ ohun ti mo ṣe lori oku Mohbad – Iyabọ Ojo

“Mo ṣe gbogbo nnkan to wa nikaapa mi lati ja fun idajọ ododo lori oku Mohbad, amọ mi o mọ pe bi gbogbo ẹ ṣe maa ri niyi. Ka ni mo mọ pe ọrọ le waa ri bayii ni,

 nnkan kan ti mo le sọ pe mio ba ti ma ṣe ni ba a ṣe kọwe ẹsun pe kijọba lọọ hu oku rẹ lẹyin ti wọn ti sin in. Emi ati ajọ ajafẹtọọ-ọmọniyan mi iba ti ma beere iru nnkan bẹẹ.”

Iwọnyi lawọn ọrọ to n jade lẹnu ilumọ-ọn-ka oṣere tiata to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan nni, Iyabọ Ojo, nigba to n sọrọ lori ipa to ko lori ọrọ iku ọdọmọde olorin hipọọpu nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ti gbogbo eeyan mọ si Mohbad.

Iyabọ Ojo sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere lori eto ayelujara kan, Talk to B, eyi ti oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ, Abiọla Adebayọ ṣatọkun rẹ lọsẹ akọkọ ninu oṣu Kinni ọdun 2025 yii.

Iyabọ ni ọtọ ni afojusun oun nigba tawọn bẹrẹ si i ja fun idajọ ododo lori iku oloogbe naa, ọrọ bi ijọba yoo ṣe tuṣu desalẹ ikoko ki gbogbo aye le mọ iku to pa a, ati ohun to ṣokunfa iku naa, ki wọn si le fiya jẹ ẹnikẹni to ba lọwọ ninu bi wọn ṣe da ẹmi rẹ Mohbad legbodo lawọn gun le, afi bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ si i fẹju si i, ti awọn nnkan mi-in si n yi wọ ọ.

“oku naa ṣi wa ni mọṣuari sibẹ, iyẹn ri bakan lara mi, mo kabaamọ”

Iyabọ ni: “Laaarin kan, mo gbọ pe Baba Mohbad ni dandan ni ki wọn ṣe ayẹwo ẹjẹ fun Liam, ọmọ Oloogbe, mo si gbọ pe ile-ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn lọọ ṣayẹwo naa. Amọ ọrọ ti Wumi, ti i ṣe iyawo Mohbad sọ ni mo n gbọ, mi o tii lanfaani lati gbọ tẹnu Baba ọkọ rẹ, tori Wumu ni oun ni awọn gbedeke kan lori ayẹwo naa, bẹẹ naa si ni Baba ọkọ rẹ.

“Ọrọ mọlẹbi ni, wọn kan n ti ọrọ siwaju sẹyin laarin ara wọn ni. Eyi ni ko jẹ ki wọn ti sinku Mohbad latigba ti wọn ti hu jade, o si baayan lọkan jẹ gidi. Mo mọ pe gbogbo nnkan ti wọn nilo lati ṣe ayẹwo DNA, gbogbo nnkan ti wọn fẹẹ mu lara oku naa ni wọn ti mu, ṣugbọn Baba Mohbad ṣi taku pe wọn ko gbọdọ sinku ọmọkunrin naa, oku naa ṣi wa ni mọṣuari sibẹ, iyẹn ri bakan lara mi, mo kabaamọ nipa ẹ, tori ti mi o ba gbarata nigba yẹn pe ki wọn lọọ hu oku naa lati ṣewadii ni, bi wọn ti ṣe sin in nigba yẹn naa ni ọrọ iba ti pari sibẹ.”

Bakan naa ni arẹwa oṣẹre ti ọrọ da ṣaka lẹnu rẹ yii fikun un pe didakẹ toun dakẹ lori ọrọ iku Mohbad ki i ṣe ti ojo, amọ gbogbo ọrọ mi-in to n yi wọ ọ, ati bawọn kan ṣe n fi ete abuku kan oun lori iṣẹlẹ ọhun, boya nitori ipa toun ko lori ọrọ ti ọmọdebinrin ti wọn tori ẹ ran Baba Ijẹṣa lẹwọn, eyi lo jẹ koun sinmi agbaja na, o loun ri i pe ọrọ ti DNA mumu laya mọlẹbi Mohbad ju ọrọ ti iku rẹ lọ, oun si gbagbọ pe adakẹ-dajọ ni Ọlọrun. O ni oun ko ni ẹnikẹni sinu, ohun ko si ṣabosi kan pẹlu Wumi, Iyawo Mohbad, oun kan fẹ lati ṣeranwọ ni toun ni, gẹgẹ bo ṣe wi.

Ẹ o ranti pe ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an ọdun 2023 ni Mohbad ku. Titi dasiko yii ni awuyewuye ṣi n lọ lori iku ati oku rẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search