Eyi lohun to ṣẹlẹ lọjọ ti Iyabọ Ojo sin ọmọ rẹ re’le ọkọ

Iroyin idunu nla gbaa lo je ni’gba ti oro de’gboro wipe Priscilla omo Iyabo Ojo, ti re ile-oko. Gele bii mama e, odu ni Priscilla je laarin ilu, paapa julo laarin awon ewe iwoyii, ta mo si Gen Z. Oju to pa’wo ni Priscilla je, ohun gaan lao ba maa pe ni omo-jo-mummy, ti irisi t’ohun ti’wa. Se won kuku ni omo o ni ba ipele iya re ko si aso da.

Lojo eti Friday to koja l’awon aworan to j’oju n gbese jade l’oju’po ikani ibanidore Instagram Iyabo Ojo ti awon miran tun mo si Queen Mother nibi to ti ni ohun dupe l’owo Oluwa fun aseyori igbeyawo ibile laarin omo re Priscilla ati oko re Juma Mkambala ti opo tun mo si Juma Jux to je olorin takasufe lati orile-ede Tanzania amo ti ogo re tin tan wo orile-ede Naijiria bayii. Koda, lati sami bo ti tewogba asa ile yii, o pe akole okan ninu awon orin re ni ololufe.

Ko tan si’be o. Igbeyawo yii kuro ni isopo oko ati aya nikan o. Asa meji lati orile-ede ototo lo pade peluu ife ati oyaya. Koda, Priscilla fun ra e l’oju opo Instagram kede wipe “Hadiza Mkambala” n ni oruko tuntun t’ohun je. Botilejepe eyi ti won se yii ni orile-ede Tanzania l’odo awon molebi oko lo je igbeyawo asa ibile ati Nikkahi. A mo sa ti Iyabo Ojo pe aye o tii ri nkankan rara tori ayeye miran miran ti yoo pariwo laarin ilu lo n bo l’ona. N l’awon osere egbe re bii Funke Akindele, Toyin Abraham, Blessing Nkechi abbl ba ki ku orire wipe awon o le ma’ra le’le de awon ayeye nla to n bo fun ti igbeyawo naa.

Yato si Iyabo Ojo, omo re okunrin Festus naa ko gbeyin to fi mo awon molebi ati awon alasunmo miran. B’oju ti wa pe t’ese pe to, awon kan ba tun n se’beere wipe baba iyawo nko?

Abala kan ninu apapo eto igbeyawo yii to ti waye lo larinrin pupo pelu erin, ijo, orin, jije-mimu, idunu-sira-eni, ati isure ninu eyi ti Iyabo Ojo gan funra e ti fi tayo-tayo gbadura fun t’oko-t’aya Mkambala.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search