Eyi nidi ti mo fi sun ṣẹyin nidii iṣẹ tiata f’ọpọ ọdun – Bukky Wright

Oluwabukọla Sẹkinat Ajọkẹ Wright, ti ọpọ mọ si Bukky Wright, tabi Ọmọtara Johnson fidunnu pada sidii iṣẹ tiata lẹkun-un-rẹrẹ!

Lẹyin ọpọ ọdun tawọn ololufẹ rẹ ti n ṣaniyan nipa ibi to wà ati ìdi to fi pa iṣẹ tiata to yan laayo ti, ti ko lọ soko ere mọ, ti wọn ko sí ri i ninu fiimu agbelewo gẹgẹ bo ṣe máa ń ṣe tẹlẹ mọ, agbà-ọ̀jẹ̀ oṣere-binrin tíátà (theatre) yii, Abilekọ Oluwabukọla Sẹkinat Ajọkẹ Wright, ti ọpọ eeyan mọ sí Bukky Wright ti sọrọ jade, lori awọn ìpènijà àti ìṣòro tó ní pẹlu aarẹ ọkan, o sọ nipa ina to jo o labẹ aṣọ ati b’awọn ọmọ rẹ̀ ṣe ràn an lọwọ lati b’omi pa’na naa nigbẹyin.

 

Bukky Wright sọrọ̀ náà lórí ètò tẹlifiṣan ori ayelujara kan ti wọn n pe ni Teju Babyface, nibi ti wọn ti f’ọrọ wa a lẹnu wo laipẹ yii.

Oṣèré-bìnrin náà sọ nípa bi ìrẹ̀wẹ̀sì, aibalẹ ọkan àti ki gbogbo nnkan ṣadeede toju su’ni, ṣe ba òun fa a lọpọ ọdun, eyi to mu kí òun sún ṣẹyin nidii iṣẹ tiata taye mọ mọ òun, t’oun ko sí kopa ninu ere kankan mọ.

Ó tun ṣàlàyé lori bó ti bẹ̀rẹ̀ sí i lo àwọn oògùn kan tí yóò mú ọ̀ràn náà kúrò ń’ilẹ̀, ó m’ẹ́nu bà á pé àwọn ọmọ òun ló ran òun lọ́wọ́ láti le borí ìṣòro yìí l’áwọn àsìkò náà.

Ṣe Yooba bọ, wọn ni bo ṣe n ṣe iṣu, ọ̀bẹ lo yé, oṣere-binrin ẹni ọdun mẹtadinlọgọta yii sọ pe oun ṣafẹri awọn ọmọ oun púpò, oun sí sìkẹ wọn, Ó lawọ́n ní òpó tí òun fẹ̀yìn tì, awọn lejika ti ò jẹ kaṣọ o bọ lọrun oun ati pe awọ́n ọmọ oun ni ẹni àkọ́kọ́ tó le tete mọ bo ṣe ń ṣe oun, tó fi mọ́ àríwísí rẹ̀.

Fun àpẹẹrẹ, Bukky ni awọn ọmọ oun ló rọ òun láti jawọ ninu ṣíṣe àníyàn ati ìyọnu, kí òun sì fún ara ní ìsinmi bo ṣe yẹ.

Latari bẹẹ, o ni gbogbo ayé òun loun fi fẹ́ràn wọ́n, gẹ́gẹ́ bí awọn naa ṣe fi ifẹ́ han si oun.

Ẹ o ranti pe lọdun 2024 tó kọja yii, ọ̀pọ̀ awọn ololufẹ obinrin naa at’awọn to fẹran ere tiata ló dáwọ̀ọ́ idunnu pé, Bukky Wright ti padà sídii iṣẹ tíátà ní Nàìjíríà.  Èyí ṣẹlẹ lẹ́yín ọ̀pọ̀ òdún tó ti fi iṣẹ́ naa sílẹ̀.  Arẹ̀wà òṣèré-bìnrin náà, ti wáá kópa nínúu eré àgbéléwò kan, tí àkọlé rẹ́ ń jẹ́ Red circle, tí Nora Awolowo gbé jáde, gẹ́gẹ́ bó ti wà lóríi ẹrọ ayelujara níbi tí Nora Awolowo ti kede pé ki àwọn èèyàn to ń béèrè fún Bukky Wright, kí wọ́n máa retí rẹ̀ nínú eré àgbéléwò náà.

Ọmọ bibi ilu Abéòkúta, nipinlẹ Ogun ni Bukky Wright, o si ti laami-laaka nidii iṣẹ tiata, bo tilẹ jẹ pe o tun máa n ṣe àwọn okoowo pẹẹpẹẹpẹẹ. O sì dije fún ipo oṣelu lọdun 2014, amọ ko wọlé.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search