Oṣerebinrin Sandra Okunzuwa ti sọrọ lori bi ọrẹkunrin rẹ tẹlẹri ṣe ja silẹ nitori oun fẹnukonu pẹlu oṣerekunrin ẹgbẹ rẹ ninu sinima.
Nigba to n sọrọ lori eto kan ti wọn pe si Sandra ṣalaye bi ẹni t’oun fẹ tẹlẹ ṣe kọ oun silẹ nitori ẹnikan fi fọnran latinu sinima kan to ṣe nibi ti oun ti fẹnukonu pẹlu oṣerekunrin ẹgbẹ oun ranṣẹ si leyi to fa ko fi opin si ibaṣepọ aarin awọn.
O tẹsiwaju pe ọpọ awọn eeyan o mọ pe kii ṣe didun inu awọn oṣere lati maa fẹnukonu ninu sinima. O ṣalaye pe nibi ti wọn ba ti n ya iṣẹ naa awọn eeyan le to ogun niye nibẹ ti oludari sinima naa a maa sọ nkan ti wọn fẹ ki wọn ṣe.
Oṣerebinrin naa ṣafikun pe to ba ṣeeṣe ki wọn yọ awọn ibi to ba niṣe pẹlu ifẹnukonu ninu sinima, oun faramọ t’oun dẹ mọ pe ko ni da awọn eeyan duro lati ma wo awọn sinima naa.
O ṣalaye pe awọn apa sinima to ba niṣe pẹlu ifẹnukonu maa n fa wahala fun awọn oṣere to si maa ṣokunfa k’awọn padanu ibaṣepọ lọpọ igba.
Sandra ṣafikun pe oun o le da awọn eeyan ti wọn ba l’awọn o le fẹ oṣere lẹbi nitori gbogbo eeyan lo mọ ohun ti wọn le gba ninu ibaṣepọ wọn.