Davido olorin fariga lori oṣelu ipinlẹ Ọṣun, o tu bii ejo si Ọga Ọlọpaa
Rogbodiyan oṣelu ati ija igboro to n lọ lọwọ nipinlẹ Ọṣun ti gba ọna mi-in yọ bayii, o ti di eyi tawọn ilumọ-ọn-ka oṣere n da si, ọrọ naa si ti n fẹju kankan lori ẹrọ ayelujara, pẹlu bi gbaju-gbaja onkọrin taka-sufee nilẹ wa nni, David Adeleke, ti gbogbo aye mọ si Davido, ṣe fa ibinu nla yọ laṣalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji, ọdun yii, to si fariga fun ọga ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, CP Umar Abba, o ni olori awọn agbofinro naa ti gbabọde, ọbayejẹ ẹda ni, awọn si maa ba a mu nnkan nilẹ, awọn maa ba a fa surutu to le gidi.
Adedeji Adeleke
Ademola Adeleke
Oyetola
Ṣe ṣaaju asiko yii ni ọrọ iyọnipo awọn alaga ijọba ibilẹ gbogbo nipinlẹ Ọṣun ati ọrọ eto idibo sipo alaga kansu to fẹẹ waye laipẹ yii ti n da lọgbọ-lọgbọ silẹ nipinlẹ ọhun, paapaa julọ laaarin ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, to lewaju awọn ẹgbẹ oṣelu alatako, ati Peoples Democratic Party, PDP to wa lori aleefa lọwọlọwọ.
Ẹ o ranti pe Ọgbẹni Gboyega Oyetọla tii ṣe
Gbogbo ijoba ibile ni ipinlẹ Ọṣun
Minisita fun eto ọrọ-aje ori omi lasiko yii, ni gomina ana nipinlẹ Ọṣun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, oun si ni aṣaaju ẹgbẹ naa. Gomina Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo fẹyin Oyetọla janlẹ ninu eto idibo sipo gomina to waye lọdun meji sẹyin, oun lo si gbegi dina fun Oyetọla lati lo saa meji nipo gomina. Ademọla yii jẹ aburo baba Davido, Alagba Adedeji Adeleke, ogbonkangi oniṣowo niluu oyinbo ati nipinlẹ Ọṣun.
Gomina Adeleke lo fọwọ osi juwe ọna ile fawọn alaga ijọba ibilẹ gbogbo nigba to dori aleefa, agaga nigba to jẹ ẹgbẹ APC to kogba sile lo yan wọn, o si n rọ kuku-kẹkẹ lati ṣeto idibo mi-in laipẹ, amọ awọn alaga naa kọri sile-ẹjọ, wọn lawọn ko faramọ iyọnipo awọn.
Ile-ẹjọ giga to kọkọ da ẹjọ naa ko ṣe wọn loore, niṣe ni wọn da ẹjọ wọn nu bii omi iṣanwọ, n ni wọn ba tun pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, eyi to gbe idajọ rẹ kalẹ lọsẹ to kọja yii. Ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lo fi ṣuga sinu kọfi awọn olupẹjọ yii, wọn ni iyọnipo awọn alaga kansu naa ko dara to, wọn ni ki wọn pada sọfiisi koowa wọn, ki wọn si maa ba iṣẹ wọn lọ ni.
Loju-ẹsẹ ni Gboyega Oyetọla ati ẹgbẹ APC Ọṣun ti paṣẹ fawọn alaga naa pe ki koowa wọn pada sọfiisi rẹ lọjọ Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji yii lati mu aṣẹ ile-ẹjọ ṣẹ, bẹẹ ni Gomina Adeleke ni ki ẹnikẹni maṣe dan palapala wo nipinlẹ oun, o loun ko fara mọ idajọ naa, eto idibo to n bọ lọna ni ki koowa wọn lọọ duro de, o si ke si Aarẹ Bọla Tinubu l’Abuja, pe ko pe mọlẹbi rẹ, iyẹn Gboyega Oyetọla, ko kilọ fun un lati maṣe da rogbodiyan silẹ nipinlẹ Ọṣun.
Bii ere bii awada, awọn alaga kansu kọri si ijọba ibilẹ wọn lọjọ Mọnde ọhun, amọ ohun ti wọn reti kọ ni wọn ba, awọn janduku ati awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ PDP kan ya bo wọn, wọn ṣediwọ fun wọn lati wọle, ki oloju si too ṣẹ ẹ, ija igboro ti bẹrẹ, iro ibọn ti n dun lakọlakọ, awọn nnkan ija oloro ti gbodekan, ọrọ si ti di igbẹ la a fewe, oko la a wa nnkan ọbẹ, ẹni ori yọ, o dile.
Ninu rogbodiyan yii, ITAFAAJI gbọ pe wọn fibọn gbẹmi alaga ijọba ibilẹ Irewọle, iyẹn Ọnarebu Rẹmi Abass, wọn si tun pa awọn eeyan bii mẹta mi-in lọjọ Mọnde ọhun.
Davido ati Gomina Adeleke
Iṣẹlẹ yii lo bi Davido, ti wọn tun n pe ni OBO (Ọmọ Baba Olowo) ninu pẹlu bo ṣe fẹsun kan Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun pe o n ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, eyi lo fi gba ori ikanni ayelujara rẹ lọ, tibinu-tibinu lo si fi n sọrọ taarata si kọmiṣanna ọlọpaa ọhun, o ni:
“Mista kọmiṣanna, bọwọ fun ofin! Oo ya were to wa o, oo si san lori ju wa lọ! Boya ki gbogbo wa jọ fi were wo were ni. Ojoojumọ ni maa fọnrere ẹ kaakiri aye, Ọgbẹni yii, ba mi dan an wo ko o riran wo.
“Ọgbẹni Umar Abaa, Kọmiṣannan Ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, o ti ba awọn ọmọ ẹ loju jẹ pẹlu eyi too ṣe yii o. Maa ṣe niṣo, gbogbo wa la jọ maa ya were papọ, iwọ were jatijati yii! Mista Kọmiṣanna, gbogbo wa jọ maa ku sibi ni!” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn eeyan ti sọ nipa ọrọ ti Davido, sọ yii. Bawọn kan ṣe n bẹnu atẹ lu u fun bo ṣe fa ibinu yọ, ti wọn n kilọ fun un pe ọrọ to le mu ko kawọ pọnyin rọjọ lo sọ yii, bẹẹ lawọn mi-in n bẹnu atẹ lu awọn oloṣelu ipinlẹ Ọṣun, wọn ni rogbodiyan ti ko yẹ ko ṣẹlẹ ni gbogbo eleyii.