Gbajugbaja olorin takasufe binrin Oyinkansola Sarah Aderibigbe ti gbogbo eeyan mọ si Ayra Starr lo ti fesi si ọrọ ti wọn fi bu ẹnu atẹ lu lori ẹrọ ayelujara latari aṣọ kan to ṣi ara silẹ to wọ to si fi gele le.
Ayra Starr lo wọ aṣọ igbalode pẹlu gele ilẹ yoruba lati ṣafihan bi a ṣe le fi aṣọ atijọ ati ti igbalode dara nibi ayẹyẹ kan nilu London.
Onkọrin ọmọ ọdun mẹtalelogun yii lo fesi lẹyin ti aworan aṣọ naa tan ka lori ẹrọ ayelujara pe gbogbo ọrọ t’awọn eeyan sọ nipa aṣọ t’oun wọ ko tu irun kankan lara oun.
Nigba to n fesi ninu abala ariwisi rẹ lori itakun ibanidọrẹ Instagram lẹyin ti ọpọ awọn ololufẹ fẹnu ṣaata imura rẹ, o ni ki gbogbo wọn lọ simẹdọ nitori oun ti wọn aṣọ to buru ju eyi to wa ninu aworan naa t’oun dẹ ṣi ma wọ eyi to tun buru ju iyẹn naa lọ nitori naa ki wọn di ọrọ ẹnu wọn mu.
Ayra Starr to ja gbangba pẹlu orin rẹ ni ọdun 2021 ni ọpọ awọn eeyan ti bu ẹnu atẹ lu imura rẹ pe ko daa to.
Esi to fi yi ti wa mu ariwisi oriṣiriṣi jade nitori bi awọn ololufẹ rẹ ṣe n ki kaare bẹẹ l’awọn kan n fẹnu ṣaata imura ati esi to fi nipa imura naa.