Ayẹyẹ ọjọọbi Baba Olowo, wọn ti ilu Abuja pa ni o!

Cubana Chief Priest, Obi Cubana fi owo dabira l'Abuja lọjọọbi rẹ

Yoruba bọ, wọn ni àrà ko le tan ninu alárà! Bi owo ba si wa, ti agbara lati da àrà ba wa, o fẹrẹ jẹ pe ko si àrà teeyan ko le da tan. Eyi lo difa fun bi ayẹyẹ ọjọọbi ọkunrin olowo yalumọ to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta nni, Obinna Iyiegbu, ti ọpọ eeyan mọ si Obi Cubana ṣe di nnkan àwò-da’mi-ẹnu, to si di iroyin ko to afojuba fun ọgọọrọ eeyan to ri ara kenge oriṣiiriṣii ati bi olowo ṣe n fi owo da bira to waye nibẹ. Koda titi di ba a ṣe n sọ yii, ori ẹrọ ayelujara ṣi n ja ranyin fun ọrọ pati naa.
Otẹẹli to gbajumọ tawọn ọlọla maa n lo nni, Transcorp Hilton Hotel to wa lagbegbe Maitama ni ilu Abuja, ti i ṣe Olu ilu ilẹ wa ni ayẹyẹ to kẹjẹgbẹ naa ti waye, ṣe Abuja ni ọkan lara awọn ile ariya ti Obi Cubana n ṣakoso rẹ wa, yatọ si ti ile ijo Eko to wa lagbegbe Lẹkki, eyi si lawọn ololufẹ baba naa tun fi maa n pe e ni Cubana Chief Priest, latari bi ọkunrin alafẹ naa ṣe n tẹ awọn ọlọla, olowo lọrun daadaa bi wọn ba lọọ gbafẹ lawọn ile ijo rẹ gbogbo, ṣe wọn ni Olowo ṣohun gbogbo tan!
Lopin ọsẹ to kọja yii, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila oṣu Kẹrin ni ariya ọjọọbi aadọta ọdun, 50 years Obi Cubana loke eepẹ. O si ti da aṣa ọpọ eeyan lati maa ṣayẹyẹ to fakiki bi wọn ba pe ọmọọdun bii ogoji, aadọta, ọgọta ati bẹẹ bẹẹ lọ, tori igbagbọ wọn ni pe ọmọde ọjọun ti ṣe kẹrẹkẹrẹ di agbalagba wayi.

Bo tilẹ jẹ pe ọmọ ẹya Igbo, ọmọ bibi ipinlẹ Anambra ni ọkunrin alafẹ yii, o fẹrẹ ma si oriṣii ẹya miiran lawujọ wa ti ko pesẹ tan sibi ayẹyẹ naa, bawọn olowo, ọlọla lati ẹya igbo ṣe rọ wọle, bii Alagba Peter Obi, ondije funpo aarẹ lẹgbẹ Labour Party, Sẹneto Chris Ngige, Olori aṣofin ana Emeka Ihedioha,  Sẹnetọ Dino Melaye ati bẹẹ bẹẹ lọ, bẹẹ lawọn eeyan pataki pataki nilẹ Yoruba, ilẹ Hausa wa nibẹ, awọn ti oke okun naa ko si gbẹyin, bi owo baaluu ṣe wọn to, ọpọ ololufẹ baba naa ni wọn fo loke, ti wọn si balẹ si pati ọjọọbi Obi Cubana, ko si ṣẹṣẹ digba ta a ba mẹnuba awọn olorin bii P square, oṣere tiata bii Ini Edo, Ebuka Obi-Uchendu, Kanayo O Kanayo, Mercy Eke, Tacha Akide, tori wọn ti yapa ju, awọn elere hipọọpu, awọn adẹrin-in poṣonu bii Broda Shaggi, Oke Bakassi, atawọn abolode-fẹ-ẹ-loju gbogbo.
Beeyan ba de ibi ti wọn paaki ọkọ si, tọhun yoo ro pe ko tun ṣẹku mọto nigboro mọ ni, latari bi tinu-tode ṣe kun fọfọ, fawọn mọto dẹndẹ-dẹndẹ, ọkọ bọginni loriṣiiriṣii, bẹẹ lawọn imura ati iwọṣọ to jojunigbese lọ janti-rẹrẹ, oge ṣiṣe ti ko lonka, ounjẹ ti ko ṣe e ka tan, ọti lile ati olomi ọsan rẹpẹtẹ. Ko si ohun teeyan fẹ ti ko si nibẹ.

Bẹbẹ kan ti ọkunrin naa ṣe ni ti awọn fọto rirẹwa fẹrẹgẹjẹ oriṣiiriṣii to ya kaakiri agbegbe ile ariya naa, ati kaakiri ilu Abuja lati polongo ọjọọbi rẹ. Ohun to tun yaayan lẹnu nipa awọn fọto naa ni pe kii ṣe fọto ẹnikan, amọ oun ati idile rẹ ni, bo ṣe jokoo, to gunwa bii ọba, bẹẹ ni iyawo rẹ, Lush Eby, wa lẹgbẹ rẹ, tawọn ọmọ rẹ ọkunrin marun-un si rọgba yii ka, gbogbo wọn wọṣọ oriṣii kanna, wọn mura ni ti aṣa ilẹ Igbo, pẹlu ilẹkẹ ọwọ ati tọrun, aworan naa ma rẹwa yeye o!

Lori ẹrọ ayelujara, loju opo ikanni rẹ, ọmọ ọlọjọọbi yii kọ ọrọ iwuri kan sabẹ awọn fọto rẹ ọhun, o ni: “Aṣeyọri mi to tobi julọ ko wa latinu okoowo mi o… ibi yii lo wa, awọn niyi. Idile mi ni ayọ mi, ireti mi, ati ipinnu mi.”
Bẹẹ niyawo rẹ naa kọ ọrọ iwuri si Olowo ori rẹ, o ni: “Lọjọ pataki rẹ yii, ẹbun to tobi julọ ti mo le fun ẹ ni ki n jẹ koo tubọ gbaju mọ Ọlọrun. O mọ ẹ daadaa ju ẹnikẹni miiran lọ, o si loye idi toun fi da ẹ. O kuu ọjọọbi yii o. Bi mo ṣe nifẹẹ rẹ to kọja eyi ti mo le kọ lọrọ silẹ lọ!”
Gẹgẹ bii akọle kan tiweeroyin Vanguard fun ayẹyẹ ọjọọbi naa, ko si irọ nibẹ rara o: “Obi Cubana ti ilẹkun ilu Abuja pa lati ṣayẹyẹ ọjọọbi aadọta ọdun rẹ” ni.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search