Ọdun Ẹgbaliganza Gb’ogo Ẹgba Alake Yọ Bi Ọjọ

Ẹsẹ o gb’ero ni’lu Ẹgba Alake lana ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2026 yii ni’bi ọdun Liṣabi ẹlẹkọkandinlogoji (39th) iru rẹ, ni’bi ti obitibiti awọn ọmọ Ẹgba ni’le l’oko ati awọn ololufẹ ilẹ kaakiri agbaye ti pejọ lati ṣe ọdun alarinrin naa.

Ọkan-o-jọ-kan awọn ọtọkulu ilu bi Aarẹ tẹlẹri – Olusẹgun Ọbasanjọ, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun – Ibukunle Amosun, Aarẹ Ọna Kakanfo – Iba Gani Adams to fi mọ awọn amuludun ati ẹni-igba-oju-mọ bii oṣere Muyiwa Ademọla, Ẹbun Oloyede (Ọlaiya Igwe), s’ọrọ-s’ọrọ Alhaji Bashiru Adisa (Baba Gboin), oṣere Olu Olowogemo (Portable Harejan); onifuji Sule Alao (Malaika) onifuji Sule Adio (Atawẹwẹ) l’aarin awọn miiran, oniJuju Sir Shina Peters (SSP).

Awọn aṣoju lati bi orilẹ-ede aadọta (50) l’agbaye ti wọn fi iwe pe naa ko gbẹyin. Aṣọ-oke ati adirẹ to gba’yi ni ọgọrọ awọn olukopa ni’bi ọdun Liṣabi ko si ti wọn fi ba kabiesi Ọba Gbadebọ Adedọtun, Alake ti ilẹ Ẹgba kẹ’yẹ.

L’ọwọ yii, oniruuru aworan ati fọnran to jẹ-oju-ni-gbese lo ti lu igboro pa paapaa julọ l’ori ayelujara lati ibi ọdun Liṣabi.

Ẹwẹ, ọpọ lo ti n wo’ye pe yatọ fun ọdun Ọlọjọ ni’lu Ile-ifẹ, ọdun Ojude-Ọba ni’lu Ijẹbu-Ode, ati ọdun Ọṣun-oṣogbo ni’lu Osogbo, ọdun Liṣabi ni ilẹ Ẹgba naa ti n di ọdun apewawo ni’lẹ Yoruba l’atari bi ọdun naa ṣe jẹ alarinrin l’ọna to ya l’ara ọtọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search