Gbajumọ Ori Ayelujara, Cute Abiọla Gbọ Ọrọ Buruku Nitori Fọnran Ibimọ Iyawo Rẹ To Fi Sita

Gbajugbaja amuludun lori ayelujara, Abdulgafar Ahmad Oluwatoyin ti ọpọ mọ si Cute Abiọla ni awọn kan ti n sọrọ kobakungbe si nitori fọnran aṣalaye (documentary) bi iyawo rẹ ti n rọbi ati ibimọ to gbe jade lori ayelujara ni ikanni YouTube.

Cute Abiọla ẹni ti oun ati aya rẹ ṣẹ gbalejo ọmọ tuntun to jẹ ẹlẹẹkeji fun wọn, lo ti n fi oniruuru fọnran ti wọn ti ṣe pamọ ṣaaju ibimọ sita. Fọnran akọkọ ni bi awọn ẹni igba ojumọ to jẹ ọrẹ mọlẹbi wọn ti n sọ asọtẹlẹ boya ọkunrin abi obinrin ni ọmọ naa yoo jẹ. Ọpọ awọn gbajumọ amuludun bi Fẹmi Adebayọ, Funkẹ Akindele, Kiekie ati bẹẹ bẹẹ lọ lo kopa ninu rẹ. Amọ ṣa akọ ni ọmọ pada jẹ.

Fọnran ẹlẹẹkeji ti wọn yoo fi sita nipa ọmọ tuntun naa ni ti asiko ibimọ, Cute Abiọla ati aya rẹ lo ka aworan gbogbo bi nnkan ṣe lọ silẹ, lati ipo irọbi de igbẹbi nipasẹ iṣẹ abẹ, ati bi oun naa ṣe n bara jẹ, gba adura pe ki iya ọmọ naa o sọ layọ.

Fọnran yii gan lo da ariwo silẹ nigba ti ọpọ awọn eniyan koro oju si Cute Abiọla pe ko tọna fun lati lo asiko ti aya rẹ wa ni ipo ẹlẹgẹ latari ibimọ nipasẹ iṣẹ abẹ lati fẹ pa owo lori ayelujara. Ibu ẹnu atẹ lu yi pọ to bẹẹ gẹ ti awọn miran n beere pe n jẹ o ṣeeṣe ki ọkan baba ọmọ o balẹ de ibi kika aworan lasiko ti iya ati ọmọ wa ni ẹsẹ kan aye ati ọrun latari ibimọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search