Ẹ Ma Da Atiku Lohun, Tinubu Yo Pari Ọdun Mẹjọ – Ile-iṣẹ Aarẹ

Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ latari Olùdámọ̀ràn Pàtàkì sí Ààrẹ lórí Ìròyìn àti Ọgbọn Inu, Bayo Onanuga, ti kọ́ ọ̀rọ̀ tí Atiku Abubakar, igbákejì Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí lórílẹ̀-èdè yìí sọ nipa eto pínpín agbára ìṣàkóso ìjọba ní Nàìjíríà, wọ́n tẹnumọ́ pé Ààrẹ Bola Tinubu lo gbọ́dọ̀ pari ìjọba ọdún mẹjọ nibamu pẹlu ilana pinpin yiyi ìṣàkóso ìjọba àpapọ̀ kiri ẹkùn gbogbo nilẹ yii. Èyí ló n jade gẹgẹ bi èsì sí ọrọ Atiku, nínú ìfọrọwánilẹ́nuwò to ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n, ló ti sọ pé kò sí ìlànà tó dájú tó pa ni dandan lati ma yi agbara ìṣàkóso ìjọba àpapọ̀ kiri awọn ẹkùn, ó ṣàfihàn rẹ̀ pé ẹkùn Àríwá àti ẹkùn Gúúsù ti pín àkóso orílẹ̀-èdè náà lọ́nà tí kò dọ́gba láti ọdún 1999.

Ẹwẹ, Onanuga ló fèsì pé n ṣe ni Atiku ń yí ìtàn padà, ó sì ń gbìyànjú láti dá ìlànà tí wọ́n ti ní gbé ìṣèlú gbà rú. Onanuga ni ẹkùn Àríwá àti ẹkùn Gúúsù ti ní àkókò ìṣàkóso lọ́tọ̀, wọ́n sì kìlọ̀ pé bí a bá yí ìlànà pínpín agbára náà padà, ó lè fa ìdààmú nínú ìṣèlú.

Onanuga wá rán Atiku létí pé, òun náà tí figba kan dije lábẹ́ ìlànà pinpin ìṣèlú nínú ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ti ìpinnu náà yọrí sí ìpínyà nínú ẹgbẹ́ àti ìkùnà nínú ìdìbò. O ṣalaye pé ìtẹ̀síwájú ìṣèlú yìí fi hàn pé ẹni tí kò bá tẹ̀lé ìlànà yìí lè dojú kọ ìṣòro nínú ìdìbò tó ń bọ̀.

Ní ìparí, Onanuga pé lẹ́yìn tí ààrẹ láti ẹkùn Àríwá ti parí ọdún mẹjọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó yẹ kí ẹkùn Gúúsù náà parí tirẹ̀ naa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ń tẹ̀lé ní ìṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search