Obi Ti L’oun O Ṣe Ju Ẹẹkan Lọ – Kwankwaso

Obi Ti L'oun O Ṣe Ju Ẹẹkan Lọ - Kwankwaso

Eekan oloṣelu to tun jẹ igbakeji oludije si’po aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu NDC, Rabiu Musa Kwankwaso lo ti ni gbajugbaja oloṣelu to tun jẹ oludije si’po aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu NDC, Peter Obi ti ṣe ileri, koda o tun t’ọwọ bọ’we pe saa kan pere l’oun yoo ṣe l’ori aleefa b’oun ba le wọ’le ninu eto idibo aarẹ l’ọdun 2027 to n bọ.

 

Kwankwaso lo s’ọrọ yii l’ori ile-iṣẹ amohunmaworan Channels pe Obi lo f’ara mọ adehun yii nitori ki agbara o le yi kan ẹkun ariwa orilẹ-ede yii l’ẹyin saa kan ọdun mẹrin ti ẹ, l’eyi to si wa ni’bamu pẹlu ilana ati aato ẹgbẹ oṣelu NDC ti wọn jọ wa.

Kwankwaso to tun jẹ gomin tẹlẹ ri ni’pinlẹ Kano ni oun ko ṣe iye meji rara l’ori adehun yii nitori oun mọ pe Obi yoo ṣika adehun naa ni’gba ti asiko ba to. Kwankwaso ni pẹlu ohun t’oun ti mọ ni’pa Obi l’ẹnu ọjọ mẹta yii, oun mọ pe ko ni s’ọrọ ko l’oun o ṣo bẹẹ mọ mọ. Alapọnle ẹda kan ni.

Gbajumọ oloṣelu lati ilu Kano yii tun tẹsiwaju gẹgẹ bii esi si ibeere ti wọn bi, o ni adehun t’awọn t’ọwọ bọ gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu wa, eyi to jẹ t’aarin awọn mejeeji naa tun wa pẹlu.

O tẹsiwaju pe, ipo igbakeji t’oun t’ẹwọ gba jẹ ajọmọ wọn ni’gba t’oun ti mọ pe l’ẹyin ọdun mẹrin, agbara yoo pada si ẹkun ariwa.

Nigba ti wọn beere pe “n jẹ yoo dije du’po aarẹ l’ọdun 2031?”, o f’esi pe k’awọn kọkọ yanju ibo 2027 tan naa.

 

Bẹẹ o ba si gbagbe, Obi fun’ra rẹ l’atẹyin wa naa ti sọ ri daadaa pe ” aarẹ oni-saa-kan ni mo fẹ jẹ nitori ki nnkan ma ba daru. N ko ni duro ọjọ kan pẹ ju ọdun mẹrin lọ, koda ki wọn o na ibọn si mi l’ori.”

Oriṣiriṣi l’awọn eeyan ti n sọ l’ori ọrọ Kwankwaso yii pe awọn ti ni adehun, t’awọn si ti t’ọwọ bọ iwe. Awọn kan n pe Obi yatọ ninu oloṣelu, bo ba ti wi ni o ṣe. Bẹẹ l’awọn miiran n pe kosi oloṣelu kan ti eeyan le fi ojo rẹ gbin’ka ayafi ẹni to ba fẹ ki oju rẹ o bo.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search