Malema Oloṣelu South Africa Sọrọ Gba Awọn To NLe Awọn Ajeji Kuro

Gbajugbaja oloṣelu alatako ni orilẹ-ede South Africa, Julius Malema lo ti bu ẹnu atẹ lu awọn ọmọ orilẹ-ede naa to n ṣe ikọlu abi le awa ajeji kuro ni ilẹ wọn.

Ogbontarigi ajafẹtọ yii sọrọ nibi eto kan lanaa Ọjọbọ Thursday, tẹle iroyin ikọlu ati lile kuro nilu lat’ọwọ awọn ọmọ onilu si awọn aare (ajeji)to wa gbe ni orilẹ-ede South Africa, to si n beere pe kinni ere wọn lẹyin ti awọn onikorira ẹda to n ṣe ikọlu si awọn alejo lati awọn orilẹ-ede bii Naijiria, Ghana, ati Zimbabwe to wa gbe pẹlu wọn ni orilẹ-ede South Africa.

"O di iṣẹ melo to ti wa nilẹ, lẹyin ikọlu si awọn ọmọ Naijiria, Ghana ati Zimbabwe to n gbe ni orilẹ-ede South Africa?

“Awọn ti ko ni iṣẹ, ti ko labọ to n sọ pe awọn ajeji lo n ji iṣẹ awọn gba. Ṣe iṣẹ ti wa wa fun wọn bayii?”
Maleema ẹni to gbajumọ fun pipe fun iṣọkan awọn adulawọ ati dida aabo bo ẹtọ awọn adulawọ lati orilẹ-ede miiran to wa ni orilẹ-ede South Africa, pari ọrọ rẹ pe oun ko fẹ ibo lati ọwọ ẹnikẹni to ba kopa ninu ṣiṣe ikọlu abi lile ajeji kuro nilu lọna aitọ, bẹẹ si ni oun ko nilo ibo lọwọ oludibo to ba n beere pe ki oun korira adulawọ ẹgbẹ oun.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search