Ijọba apapọ ti wọgi le fifi Oye Dokita s’orukọ fawọn ti wọn fi oye naa da lọla yala lẹnu iṣẹ tabi lori iwe. Wọn ni lilo oye ohun yoo fa iruju fun awọn ti wọn kawe gboye Dokita naa ati pe nibayi o ti wa di ohun ti ko b’ofin mu lati fi oye naa si orukọ ti ijiya ofin yoo si wa f’ẹni to ba ṣe bẹ.
Minisita fun Eto Ẹkọ lorilẹede Naijira, Tunji Alausa lo sọ eyi di mimọ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Abuja. Nigba to n sọrọ, Alausa ni Igbimọ Alaṣẹ apapọ buwọlu aṣẹ naa fun fifun ati lilo oye idalọla lat’ọwọ awọn Ile-ẹkọ giga ilẹ wa.
O ṣalaye pe aṣẹ yii ni lati fi opin si pinpin oye idanilọla dokita bo ṣe wun wọn nitori owo tabi anfaani oṣelu ati ki awọn le da iyi to wa nibi kika iwe gboye Dokita pada lati jẹ koriya f’awọn araalu.
Minisita fun Eto Ẹkọ lorilẹede Naijira, Tunji Alausa
Labẹ ofin tuntun yii, awọn ti wọn ba fi oye dokita naa da lọla o ni anfaani lati fi kun orukọ ati pe ti wọn ba fẹ lo nibi kikọ orukọ, wọn gbọdọ ṣafihan pe oye idalọla ni lati fi han gbangba pe wọn o kawe gba.
Alausa tẹsiwaju pe ofin yi fi gbendeke le irufẹ awọn oye idalọla naa ti wọn si din ku si mẹrin pere to jẹ Ẹkọ ofin, imọ sayẹnsi, imọ litireṣọ ati ọrọ ọmọniyan.
Ofin yii tun wa fi ofin de awọn Ile-ẹkọ giga ti wọn ko lanfaani lati ni ikẹkọ gboye Dokita lati ma fi oye naa da awọn eeyan lọla mọ lati da awọn Ile-ẹkọ giga ti wọn ṣẹṣẹ n bẹrẹ ti wọn ko tii lẹtọ si kikẹkọ gboye Dokita ti wọn si fi n da awọn eeyan lọla lẹkun.
Lati bii ọdun mẹwa sẹyin ni awuyewuye ti n jẹyọ lori fifi oye dokita da awọn eeyan lọla fun anfaani owo tabi oṣelu. Ni ọdun 2012 ni Agbarijọpọ awọn Ọga Agba Ile-ẹkọ giga lorilẹede Naijira ṣe ipade pọ lati f’ofin de irufẹ idanilọla naa ṣugbọn ko fidimulẹ labẹ ofin gẹgẹ bi Alausa ṣe sọ.
Nibayi, Alausa ni Ile-iṣẹ ijọba to n risi ọrọ Ẹkọ ati Ajọ to n risi Ile-ẹkọ giga lorilẹede yii yoo kọwe ranṣẹ si awọn ti ọrọ kan ni Ile-ẹkọ giga gbogbo lati gbọ ikilọ. O fikun pe awọn maa bẹrẹ si ni tẹlẹ ayẹyẹ ikẹkọ gboye lati rii pe ofin naa fidi mulẹ.