Ilumọọka oṣerebinrin nni, Lizzy Anjorin ti gba lati ba oṣerebinrin ẹgbẹ rẹ, Iyabo Ojo na tan bi owo ninu ifigagbaga ẹsẹ kikan lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti apatẹ ariya to jẹ Ọkọ Iyabo, Paul Okoye ti gbo aye mọ si Paulo ti pe fun ija naa.
Eleyi ti wa ṣide ija tipẹtipẹ to ti wa laarin awọn oṣere mejeeji. Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ ni Lizzy ti sọ pe nibayi, oun ti ṣetan lati wọnu gbọngan ija abẹṣẹkubiojo pẹlu Iyabo ti Paulo naa ba ti le koju ọkọ oun, Oloye Lawal ninu ija ọlọwọ mẹwa ki ija t’oun ati Iyabo to waye l’ọjọ to ba tẹle.
Lizzy wa tẹsiwaju lati pe awọn mejeeji ki wọn ṣafihan awọn ohun ini wọn nitori oun mọ pe wọn o ni ọrọ to oun ati Ọkọ oun leyi to tubọ n buna jo ija to wa laarin awọn mejeeji. O wa fikun pe k’awọn mejeeji ma f’oju di oun nitori oun o kii ṣe karimi atipe Ọkọ ti wọn n gun ko le ra ilẹ l’agbegbe ile oun.
Ti ẹ o ba gbagbe, ni ọdun 2024 ni Paulo kọkọ pe fun ija laarin Lizzy ati Iyabo to si fi owo miliọnu mẹwa naira (₦1 million) ṣe koriya fun ẹni to ba gbegba oroke.
Ija aarin awọn oṣerebinrin mejeeji yi ti bẹrẹ lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin pẹlu ija ori ẹrọ ayelujara, ipejọ Ile-iṣẹ Ọlọpa ati t’ile-ẹjọ. Ni ọdun to kọja ni Iyabo Ojo fi ẹsun ibanilorukọ jẹ kan Lizzy to si n beere fun owo to to biliọnu kan naira (₦1 Billion) bi o tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ da ẹjọ naa nu. Iyabo ti sọ pe oun ṣi ni lọkan lati da ọrọ naa pada s’ile-ẹjọ. Eyi ti wa fa rirugbo ija aarin wọn naa si ti ko si jọ pe yoo pari laipẹ.