Goodluck Jonathan Yari Lori Idije Dupo Aarẹ L’ọdun 2027

Aarẹ tẹlẹ ri l’orilẹ-ede Naijiria, Ọmọwe Goodluck Jonathan ni awọn kan korajọ lọ ba ni ọfisi rẹ to wa nilu Abuja lati kesi fun idije du ipo aarẹ ni ọdun 2027.

Awọn olufẹhonuhan naa ti awọn obinrin ati ọdọ pọ ninu wọn lo gbe awọn patako to ni oriṣiriṣi akọle to n kesi Goodluck Jonathan o pada wa dije du ipo aarẹ.

Nigba to n fọ esi, Jonathan dupẹ lọwọ awọn eniyan naa fun ifẹ rẹ ti wọn ni ati ifọmọniyanṣe. O tẹsiwaju lati jẹ ko di mimọ pe oun gbọ ni ṣugbọn ti oun ko ti le gba nitori awọn idi kọọkan, ti oun si n ṣe ifilọ lọwọ lati mọ iru ipinu to yẹ.

Aarẹ tẹlẹ ri l'orilẹ-ede Naijiria, Ọmọwe Goodluck Jonathan

Ko ṣai mẹnuba pe o rọrun lati wa kesi oun lati dije ṣugbọn to ṣe aroye pe onka iye awọn ti kii jade dibo pọ pupọ ju l’orilẹ-ede Naijiria. O pe “o ṣeeṣe ki idaji ninu ẹyin tẹ wa nibi o ma ni kaadi idibo rara.”

Ẹ ranti pe ṣaaju ni aya aarẹ tẹlẹ ri naa, Patience Jonathan fi idi rẹ mulẹ pe awọn kon ni erongba rẹ lati ṣe saa keji lori aleefa ṣugbọn ti iwoye ṣi n bẹ l’ori wọn lati mọ ibi ti ọrọ naa yoo yanju si.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search